Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Ẹgbẹ Agba Yoruba (Yoruba Council of Elders) ti bẹnu atẹ lu ipade tawọn gomina ṣe pẹlu ẹgbẹ awọn darandaran Miyetti Allah Cattle Breeders Association (MACBAN) niluu Akurẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Ẹgbẹ naa ni ko si aṣeyọri kankan ti ipade ọhun ṣe ju ẹjọ ti ko nitumọ ati ọrọ tawọn oloṣelu n fi gbogbo igba sọ, eyi ti ko wa ojutuu tabi opin si ifiyajẹni ati ipakupa tawọn darandaran n pa awọn ọmọ Yoruba.
Ninu atẹjade kan ti adari ẹgbẹ naa, Dokita Kunle Ọlajide, fọwọ lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ yooku, o ni ki i ṣe nnkan tawọn eeyan fẹẹ ri ni wọn ṣe nibi ipade ọhun, awọn to si kora wọn jọ sibẹ kan lọọ ṣere ni.
Dokita Ọlajide ni awọn darandaran wa nibẹ, awọn gomina to si fẹẹ pẹtu si aawọ to wa nilẹ naa wa nibẹ, ṣugbọn ko sẹni to ṣoju awon ọmọ Yoruba ti wọn n fiya jẹ ti wọn si n pa lojoojumọ.
Atẹjade naa ni, ‘’ Pẹlu ọkan iporuuru la fi ṣagbeyẹwo ipade tẹgbẹ awọn gomina ṣe pẹlu MACBAN niluu Akurẹ. A nigbagbọ pe ipade ti wọn ba ti fẹẹ pari aawọ gbọdọ ni gbogbo awọn tọrọ kan ninu.
‘’Ipade Akurẹ yii ja wa kulẹ gidi nitori awọn eeyan tawọn darandaran n ṣe nijamba ko si nibẹ. O yẹ ki wọn pe awọn lẹgbẹlẹgbẹ nilẹ Yoruba ti ọrọ yii kan atawọn ti iwa apaayan awọn darandaran ti ṣe lọṣẹ. O yẹ ki Pa Faṣoranti ran awọn aṣoju ẹgbẹ ibilẹ lọ sibẹ.’’
Ẹgbẹ naa ni o jọ pe ọdọ Emir Kano ni wọn ti ṣepade ọhun nitori diẹ ni awọn aṣoju Yoruba ti wọn pe, awọn gomina Iwọ-Oorun to si wa nibẹ ko ṣoju Yoruba rara nitori ẹgbẹ awọn gomina ni wọn ṣoju fun, bẹẹ ni ko sẹni to bẹnu atẹ lu bi awọn Miyetti Allah ṣe n sọ pe awọn lawọn ni gbogbo ilẹ Naijiria.
Wọn waa ni eyi fi han pe ijọba apapọ ko bikita nipa ajalu to n tọwọ awọn darandaran waye, bẹẹ ilẹ ti wọn n ja si ki i ṣe tiwọn rara, Aarẹ Muhammadu Buhari si ni lati sọrọ lori nnkan to n lọ kiakia.