Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ojubọ arumọjẹ kan wa lagbegbe Ijagun,nitosi Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun, inu igbo jingbun ni, awọn ọkunrin mẹrin kan ni wọn n dari ibẹ ti wọn n lu awọn eeyan ni jibiti owo nla, ti wọn si tun n fọ ayederu owo ilẹ okeere pẹlu.
Awọn ọkunrin mẹrin naa ni: Salau Taiwo, Ifakunle Adeyẹmi, Tajudeen Jimọh ati Adebayọ Akeem.
Lasan kọ ni aṣiri wọn tu, igbiyanju awọn ọlọpaa, OPC atawọn Fijilante kan lo jẹ ki ọwọ ba awọn eeyan naa lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 2021.
Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ogun, CP Edward Ajogun, atawọn ọmọọṣẹ rẹ ni wọn ko awọn akọroyin sodi lọ sinu igbo naa lati foju ri ibi ti wọn gbe ojubọ yii kalẹ si, ati iru ohun ti wọn n ṣe nibẹ.
Ajogun ṣalaye pe ọmọbinrin kan, Imọlẹayọ Ashade, ti ọjọ ori ẹ ko ju mẹrindinlọgbọn lọ lawọn baba mẹrin yii lu ni jibiti miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun le mẹwaa naira ( 1.310,000).
O ni ọmọbinrin to ṣẹṣẹ fẹẹ lọọ sinru ilu naa lo lọọ fẹjọ sun ni teṣan ọlọpaa Awa-Ijẹbu pe ninu oṣu kejila, ọdun 2020, meji ninu awọn ikọ ẹlẹni mẹrin yii waa ba oun fun iranlọwọ. O ni awọn baba naa sọ pe ko si ibi ti awọn le sun si, bẹẹ awọn ko mọ ibi kankan lagbegbe tawọn wa naa.
Aṣe pẹlu aṣẹ ni wọn ba Imọlẹayọ sọrọ, bo ṣe di pe ko le kọ ohun wọn niyẹn, lo ba gba lati ran wọn lọwọ, ni wọn ba tan an lọ sojubọ arumọje naa ninu igbo to wa. Wọn jẹ ko mulẹ pe ẹnikan ko ni i gbọ nipa ibi tawọn mu un wa atohun tawọn ba ni ko ṣe.
Bẹẹ lo si ṣe ti wọn gba miliọnu kan ati ẹgbẹrun lọna ọọdunrun ati mẹwaa naira lọwọ rẹ.
Nigba to n ṣalaye si i, Imọlẹ sọ pe awọn to lu oun ni jibiti naa sọ pe awọn yoo ran oun lọwọ lori okoowo toun n ṣe ni, ohun ti wọn ṣe ni koun lọọ wa owo naa wa niyẹn toun si fun wọn.
Yatọ si eyi, ikọ onijibiti yii tun n fọ owo ilẹ okeere, wọn si fi n lu awọn eeyan ni jibiti naa ni. Oriṣiiriṣii owo ilẹ okeere bii dọla, pọn-un atawọn mi-in to jẹ ayederu lawọn ọlọpaa ba nibẹ, bẹẹ ni awọn ere kanka ti i dẹru baayan naa wa nibẹ pẹlu, wọn si tun ri owo ti wọn gba lọwọ obinrin yii naa nibẹ.
Gbogbo wọn ni yoo foju ba kootu gẹgẹ bi ọga ọlọpaa ipinlẹ Ogun ṣe ṣeleri.