Florence Babaṣọla
Obinrin kan to fara han niwaju awọn igbimọ to n gbọ ẹsun awọn araalu nipa awọn ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Adebisi Khadija, ti sọ pe diẹ lo ku ki oun ya arọ latari ohun ti oun ti foju ri nipasẹ ibọn awọn ọlọpaa.
Gẹgẹ bi Khadija ṣe sọ, ‘Ọja Ifọn ni mo n lọ laaarọ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, mo wa ninu mọto, ṣugbọn bi a ṣe de agbegbe Lameco, niluu Oṣogbo, la ri i ti awọn eeyan n sa kijokijo kaakiri. Onimọto to gbe wa sọ pe ki gbogbo wa sọkalẹ, oun naa si sa fun ẹmi ara rẹ.
“Lojiji ni mo bẹrẹ si i gbọ iro ibọn lakọlakọ kaakiri, emi naa n sa sọtun-sosi, bi mo ṣe fẹẹ sa sinu ibi kan bayii ni ibọn awọn ọlọpaa ba mi ni itan (thigh). Mo ṣubu lulẹ, mo bẹrẹ si i sunkun pe kawọn eeyan ran mi lọwọ, ṣugbọn ko si ẹni to le sun mọ mi nitori ṣe lonikaluku n sa kaakiri.
“Lẹyin ti mo lo ọgbọn iṣẹju nibẹ ni awọn ọlọpaa kan de, wọn gbe mi lọ sileewosan LAUTECH, nọọsi ti a ba beere ohun to ṣẹlẹ, awọn ọlọpaa ni ṣe lawọn ṣaanu mi nibi ti mo ṣubu si, kia ni mo pariwo pe irọ ni wọn n pa, ọta ibọn ọlọpaa lo ba mi.
“Nọọsi yẹn beere pe ṣe awọn ọlọpaa ni yoo ṣe ohun to tọ lori mi tabi ki wọn bẹrẹ itọju, mo ni ki wọn bẹrẹ itọju mi. Ọkọ mi waa ba mi nibẹ, a ṣe oriṣiiriṣii ayẹwo, wọn si gbe mi lọ fun iṣẹ-abẹ akọkọ laago mẹwaa alẹ ọjọ naa, wọn sọ pe ọsẹ keji ni ma a ṣe iṣẹ-abẹ keji.
“Ọsẹ to tẹle e lawọn dokita bẹrẹ iyanṣẹlodi, wọn dari mi si OAUTHC, Ifẹ, ṣugbọn latari konilegbele to wa, wọn tun gbe mi lọ sileewosan aladaani. Ẹgbẹrun lọna ọgọta naira ni mo na lori iṣẹ-abẹ akọkọ, o din diẹ lẹgbẹrun lọna irinwo naira ni mo na lori iṣẹ-abẹ ẹlẹẹkeji, mo ṣi jẹ ileewosan ni ẹgbẹrun lọna igba naira bayii, idi niyẹn ti wọn ko fi yọ irin to wa ninu ẹsẹ mi, ti wọn ko si tọju mi mọ.
“Gbogbo iwe itọju yii ni mo ni lọwọ. Mo wa n beere fun miliọnu marun-un naira gẹgẹ bii owo itanran nitori awọn itọju ati iṣẹ-abẹ mi-in ṣi wa ti mo tun maa ṣe”
Alaga igbimọ naa, Adajọfẹyinti Akin Ọladimeji, beere lọwọ awọn ọlọpaa boya wọn ni awijare tabi wọn ko ni, ṣugbọn awọn ọlọpaa ni ko si awijare kankan.
Latari idi eyi, Ọladimeji fi da Khadijat loju pe igbimọ naa yoo dabaa owo itanran to ba yẹ funjọba, nitori ijọba nikan lo ni ẹtọ lati fun un ni owo gba-ma-binu.