Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Aṣofin to n ṣoju ẹkun Ila-Oorun Ekiti nile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Oluwajuwa Adegbuyi, ti jade laye.
Adegbuyi, ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), lo jade laye lalẹ ọjọ Abamẹta, Satide, to kọja, lẹni ọdun mọkanlelaaadọta.
Gẹgẹ bi mọlẹbi oloogbe naa kan ṣe sọ, lati Ọjọruu, Wẹsidee, to kọja, ni ọnarebu naa ti n sọ pe ori n fọ oun, awọn eeyan ẹ si ni ko sinmi daadaa, ṣugbọn ọjọ Ẹti, Furaidee, ni ọrọ naa lagbara si i, ko too pada ja si iku lọjọ Satide.
Nigba to n ba mọlẹbi Adegbuyi kẹdun, Abẹnugan ileegbimọ aṣofin Ekiti, Ọnarebu Funminiyi Afuyẹ, sọ pe ibanujẹ gbaa niroyin iku naa jẹ nitori gbogbo ile igbimọ ọhun ni ajalu ọhun kan.
Ninu atẹjade kan ti Oludamọran lori eto iroyin fun abẹnugan naa, Akọgun Tai Oguntayọ, fọwọ si, o ṣapejuwe oloogbe bii ọkan ninu awọn to dangajia ju nile-igbimọ ọhun, ṣugbọn iku ti fi da awọn aṣofin yooku loro.
O ni, ‘‘Ileegbimọ Ekiti jẹ ibi ti awa aṣofin mẹrindinlọgbọn wa, iku si ti ṣọṣẹ laarin wa bayii. O ya wa lẹnu pupọ, ṣugbọn a ko le ba Ọlọrun fa nnkan kan.’’
Bakan naa ni agbẹnusọ APC l’Ekiti, Ọnarebu Ade Ajayi, ṣapejuwe oloogbe naa bii akinkanju ati ẹni to fọkan sin, o si maa n pẹtu si aawọ to ba jọ mọ ọrọ awọn oṣiṣẹ ati ijọba.
O ni ajalu nla niku oloogbe ọhun jẹ fun ẹgbẹ naa nitori ẹni ti ọpọ eeyan n wo bii aṣaaju ni, o si ṣe iranlọwọ loriṣiiriṣii nigba aye ẹ.
Ọjọ kẹrin, oṣu karun-un, ọdun 1969, ni wọn bi Adegbuyi. Laarin asiko to lo nileegbimọ Ekiti, oun ni alaga igbimọ to n ri sọrọ iṣẹ ati idagbasoke.
Iya, iyawo, awọn ọmọ ati ọmọọya ni oloogbe naa fi silẹ saye lọ.
Nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ni wọn sin oloogbe ọhun sile ẹ to wa niluu Omuo-Ekiti, nijọba ibilẹ Ila-Oorun Ekiti.