Faith Adebọla
Awọn araalu kan ni Igangan ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe niṣe ni wọn n gbe sẹyin awọn Fulani to n huwa janduku lagbegbe naa, bẹẹ ni ọga ẹṣọ Amọtẹkun ti ko fẹ ka darukọ oun jẹrii si eyi. Wọn ni niṣe lo da bii pe ọna ijẹ awọn ọlọpaa naa ti di latigba ti Sunday Igboho ti waa le awọn Fulani kan lọ.
Ẹnikan to ba wa sọrọ sọ pe ni bayii, awọn ọlọpaa ki i fẹẹ tẹle awọn tawọn ba kegbajare lọ sọdọ wọn pe awọn Fulani tun ti gbe iṣe wọn de. O ni ko si eyikeyii ninu awọn iṣẹlẹ akọlu to waye kẹyin yii tawọn ọlọpaa ba awọn debẹ, bẹẹ ni wọn o ṣe ohunkohun si i.
Ẹsun mi-in ti wọn tun fi kan awọn ọlọpaa ni pe ti akọlu ba waye laarin Yoruba ati Fulani, to ba jẹ Fulani lo kọkọ ṣe akọlu naa, rakuraku lawọn ọlọpaa maa ṣe ọrọ ọhun, ko si ni i si ohun to maa tidi ẹ yọ. Ṣugbọn to ba jẹ awọn Yoruba ni wọn lọọ da sẹria fun Fulani tabi maaluu wọn, kia lawọn ọlọpaa maa mu awọn Yoruba ọhun, ti wọn maa bẹrẹ si i fi iya jẹ wọn.
Ọgbẹni kan to porukọ ẹ ni Bisiriyu sọ fun wa pe wọn ṣẹṣẹ fi oun silẹ ni olu-ileeṣẹ ọlọpaa n’Iyaganku, Ibadan, ti wọn wọ oun lọ ni, latari pe oun lọọ ba awọn Fulani ti wọn fi maaluu jẹ oko kaṣu oun ja, ṣugbọn wọn o ṣe nnkan kan fawọn Fulani ọhun.