Lati le wa ojuutu si wahala to n ṣẹlẹ lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, Gomina Ṣeyi Makinde, ti ṣabẹwọ sagbegbe ọhun, bẹẹ lo ti fi awọn eeyan ibẹ lọkan balẹ pe eto aabo to peye yoo wa fun dukia ati ẹmi kaluku wọn.
̀Ọjọ Aiku, Sannde ọsẹ yii, ni Ṣeyi Makinde ṣepade pẹlu awọn alẹnulọrọ lagbegbe ọhun, lara wọn ni awọn alaga ijọba ibilẹ, awọn oloṣelu lagbegbe Ibarapa.
Nibi ipade ọhun ni gomina yii ti sọ pe gbogbo wahala to de ba awọn eeyan agbegbe naa lo kan oun pẹlu, ati pe ti awọn eeyan Ibarapa ko ba roorun sun, oun naa ko le foju kan oorun.
Niluu Igbo-Ọra ni Makinde ti sọ pe bi oun ṣe waa ba wọn lalejo yii, lọgan ni ojuutu yoo de ba idaamu ti wọn n ri nipa eto aabo.
Ṣiwaju si i, Gomina Ṣeyi Makinde tun ti ba awọn eeyan agbegbe naa kẹdun gidigidi lori iku to pa Dokita Fatai Aborode. “O ni, eeyan kan ti mo mọ daadaa ni oloogbe ọhun, bẹẹ lawọn iṣẹlẹ aburu to waye lagbegbe yii jẹ ohun ibanujẹ nla fun mi.