Ki awueywye to gbode kan le dohun igbagbe patapata lori bi Oloye Sunday Igboho ṣe fẹnu abuku kan Ọọni Ile-Ifẹ, agbẹnusọ fun Arole Oodua, Ọgbẹni Moses Ọlafare, ti sọ pe baba naa ko binu mọ, kabiesi ti gba pe ọmọde lo n ṣe Igboho.
Ninu ọrọ ti Ọlafare ba awọn oniroyin sọ lo ti sọ pe Ọọni ko ni esi kankan to fẹẹ fọ si ohun ti Sunday Igboho ṣe lori bo ṣe pe e ni ẹru Fulani, nitori ipo ọba alaye naa ṣagba ko maa fesi si ohun to le da wahala silẹ nilẹ Yoruba.
O ni, “Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, ti fori ji Oloye Sunday Adeyẹmọ, ọkan lara awọn ọmọ Arole Oodua ni Igboho, baba ko gbọdọ binu si ọmọ ẹ, bẹẹ Ọọni ko ni ohunkohun to maa sọ lori ọrọ ọhun. Ohun to ṣe pataki ni pe Ọọni Ogunwusi ko tiẹ ka eebu ati ọrọ kobakungbe ti Sunday Adeyẹmọ sọ si i si, nitori pe bii ọmọ lo ṣi jẹ si Arole Oodua, niwọn igba to si ti bẹbẹ fun aforiji, baba ti dariji i.”
Ṣiwaju si i, o ni Sunday Igboho ko ṣadeede bẹ Ọọni ki Arole Oodua ma binu, o ni Ọba Olugbọn ti Ile-Igbọn ati Ọba Oluṣọla Alao, ni wọn ti kọkọ pe Igboho, ti wọn si ba a wi pe ọrọ to sọ si Ọọni ku diẹ kaato, o si gbọdọ tọrọ aforiji nitori oun ni baba gbogbo awọn ọmọ Yoruba to sọ pe oun n ja fun.
Ọlafare sọ pe, “Ko too di pe o tọrọ aforiji, Baba Olugbọn ti Ile-igbọn ti kọkọ pe Arole Oodua lori foonu pe oun ti ba Sunday Igboho wi lori aṣiṣe nla to ṣe, ati pe oun ti sọ fun un ko ṣe fidio ti yoo fi tọrọ aforiji, ti gbogbo aye yoo si ri i pe o ti ṣe bẹẹ.”
O ni ohun to fa idi ti Igboho fi ṣe fidio niyẹn, Ọba Olugbọn lo ni ko ṣe e, ati pe Ọọni paapaa ko binu mọ o, bẹẹ ni kabiesi ko ni ohunkohun to fẹẹ sọ lori ọrọ Sunday Igboho.