Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ijọba Gomina Dapọ Abiọdun ti kilọ fẹgbẹ awakọ ero NURTW, nipinlẹ Ogun, lati yago lawọn gareeji kaakiri ipinlẹ yii, bi wọn ko ba fẹẹ jiya lọdọ ìjọba.
Kọmiṣanna feto iroyin nipinlẹ Ogun, Alaaji Waheed Oduṣile, lo fi atẹjade to kede eyi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ keje, oṣu keji, ọdun 2021.
Atẹjade naa ṣalaye pe dandan ni kijọba tete kilọ fawọn ẹgbẹ naa bayii, nitori awọn ẹṣọ alaabo ti fi to ijọba leti pe awọn NURTW ipinlẹ yii ti n ṣeto bi wọn yoo ṣe tun lọọ maa gbowo kiri ni gareeji lorukọ ijọba. Bẹẹ, eyi ta ko aṣẹ ijọba to wa nilẹ, eyi to fofin de ẹgbẹ yii lati maa gbowo orita ati ti gareeji lọwọ awọn awakọ lorukọ ijọba.
Ẹ oo ranti pe ija agba to bẹ silẹ ninu ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Ogun lo fa a ti ile-igbimọ aṣofin ipinlẹ yii ṣe fofin de wọn loṣu kẹfa, ọdun 2020. Ija naa lagbara debii pe ẹmi ati dukia awọn to n ba ara wọn ja naa wa ninu ewu. Eyi lo fa a tijọba ṣe fofin de wọn latigba naa.
“A ti fun awọn agbofinro laṣẹ lati mu ọmọ ẹgbẹ NURTW ati ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ tijọba ko ba fun laṣẹ lati ṣiṣẹ, ṣugbọn to fẹẹ gbowo ni gareeji lorukọ ijọba”
Bẹẹ ni atẹjade naa wi.