Olu-Theo Omolohun, Oke-Ogun
Ile-ẹjọ kọkọ-kọkọ kan to wa niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, ti fopin si igbeyawo ọdun mọkanla to wa laarin Ọgbeni Ismail AbdulRasak, ẹni ọdun mẹtalelogoji, ati iyawo rẹ, Abilekọ Fasilat Alatiṣe, latari pe ko si ifẹ mọ laarin wọn, wọn ni ija ojoojumọ ni tọkọ-taya naa n ja.
Ọgbẹni Rasak la gbọ pe o pe iyawo rẹ lẹjọ si kootu ọhun, o si ṣalaye pe latigba tobinrin naa ti da ẹsẹ wọ ile oun, ojumọ kan, ija kan ni, ko si igbe aye alaafia laarin awọn, ko si ye oun bi awọn ṣe bi ọmọ mẹfa laarin asiko naa.
Olupẹjọ ni ọpọ igba lawọn ti ko ara awọn lọ sọdọ awọn mọlẹbi, ti wọn ti ba awọn da si aawọ to n ṣe lemọlemọ ọhun, ṣugbọn kaka ki ewe agbọn iṣoro naa dẹ, niṣe lo n le si i, iyawo oun lo si n fa a.
O ni ẹlẹjọ-wẹwẹ obinrin ni, asunkun-rojọ si tun ni pẹlu, ọpọ igba lo jẹ pe awọn nnkan ti ko yẹ ko ka kun lo maa maa ṣe ran-n-to le lori, to si maa bu oun labuuṣidii lori ẹ, debii pe oun ti di ẹni yẹyẹ loju awọn ọmọ ati laarin adugbo.
Kootu naa ni ki olujẹjọ fesi si ẹsun ti ọkọ rẹ sọ, Abilekọ Fausat to mu baba rẹ, Alaaji Yekeen, ati aburo rẹ, Ọgbẹni Ṣemiu, wa si kootu gẹgẹ bii ẹlẹrii ṣalaye pe ọkọ oun ki i ṣe ọkunrin gidi kan, ki i ṣe ojuṣe rẹ lori awọn ọmọ, o sọ poun n ṣiṣẹ loootọ, ṣugbọn o lahun si idile rẹ, oun iyawo nikan loun n da bukaata awọn ọmọ gbọ. Obinrin naa ni ibeji wa ninu awọn ọmọ oun, ṣugbọn ọkọ oun ko tori eyi ṣaanu oun rara.
Baba iyawo naa jẹrii pe ọpọ igba loun ti gba ana oun lamọran lati sera ro lori ọmọ bibi, ko le raaye tọ wọn yanju, ṣugbọn ẹyin eti rẹ lamọran oun n bọ si, niṣe lo n pa ọmọ jọ bii eku ẹda, iya gidi lo si fi n jẹ ọmọ oun ti i ṣe iyawo rẹ.
Lẹyin tile-ẹjọ ti fun wọn lanfaani boya wọn ṣi le ri ọrọ ọhun sọ laarin mọlẹbi ṣugbọn ti ko seso rere, tawọn mejeeji si yari pe awọn ko fẹ ajọṣepọ wọn mọ, Oloye Muritala ti i ṣe adajọ kootu naa paṣẹ pe ile-ẹjọ ti fopin si igbeyawo wọn. Adajọ ni ki wọn ko iwe-ẹri ọjọọbi awọn ọmọ mẹfẹẹfa naa wa lọjọ mẹjọ, ki wọn le pinnu ọdọ ẹni ti wọn maa pin wọn si, o si paṣẹ ki iyawo naa lọọ ko ẹru ẹ kuro lọọdẹ Ọgbẹni Rasak lai fakoko ṣofo.