Ọlawale Ajao, Ibadan
Bo tilẹ jẹ pe ojoojumọ lawọn ara Ayetẹ, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa, nipinlẹ Ọyọ, n pariwo pe ọkan awọn ko balẹ nipa eto aabo, awọn alaṣẹ ikọ eleto aabo ipinlẹ naa ti sọ pé alaafia ti jọba níbẹ bayii, kò sí nnkan ibẹru kan ni gbogbo agbegbe naa mọ rara.
Oludari ẹṣọ Amọtẹkun ipinlẹ Ọyọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayinka Ọlayanju, lo sọrọ yii ninu atẹjade to fi ṣọwọ sawọn oniroyin n’Ibadan laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Lati fi da awọn eeyan loju pe kò sí ohun ìpaya kankan lagbegbe Ibarapa mọ, Ajagun-fẹyinti Ọlayanju sọ pé bi ẹnikẹni tabi akojọpọ awọn eeyan kan ba fẹẹ lọ síbẹ lati já irọ́ òun tabi fìdí ọrọ oun mulẹ, oun ti ṣetán láti mú wọn tọ gbogbo ìlú tó wa lagbegbe Ibarapa lọ lọkọọkan.
Ṣugbọn ninu iwadii ti ALAROYE ṣe, a gbọ pe loootọ lọkàn awọn araalu naa ti n balẹ pẹlu bi ọpọ àwọn tó ti sá kúrò nílùú nitori wahala awọn Fúlàní ti n pada de, ṣugbọn nnkan kan ṣí n ba wọn lẹru síbẹ.
Gẹgẹ bí olugbe ilu Ayetẹ kan ṣe ṣalaye fakọroyin wa, “Ọkunrin ti wọn n pe ni Wakili yẹn náà ló ṣi n já àwọn èèyàn laya niluu Ayetẹ̀ ati nijọba ibilẹ Kajọla nitori loootọ lawọn Yorùbá to ti sa lọ tẹlẹ ti pada wa, ṣugbọn kò sẹni tó n lọ soko àlọsùn mọ nitori ibẹru Wakili yẹn.
“Agbalagba ni Wakili, ṣugbọn oun gan-an ko tun waa buru to awọn ọmọ ẹ mẹta ti mo mọ ti wọn n jẹ Abu, Sani ati Esiẹ. Ko si ibọn ti ko pe ṣọ́wọ́ awọn ọmọ rẹ yii tan titi dori ibọn Ak47 ati ibọn awọn soja.
“Gbogbo awọn Fúlàní to wa lagbegbe Ibarapa ni wọn kò dá maaluu kiri mọ, awọn ọmọ Wakili yii nikan naa ni. Awọn meji ni wọn máa n gbe ibọn AK 47 tẹle awọn ẹran wọn lẹyin. Ọpọlọpọ oko awọn eeyan ni wọn sì ti fi maaluu wọn bajẹ tan.
“Bi mo ṣe n ba yin sọrọ yii, awọn ileewe bíi mejila ni ko le lọ sileewe bayii nitori ibẹru awọn Fúlàní yii. Awọn olukọ wọn gan-an ti kọwe sí ijọba lori ẹ.
Orúkọ diẹ ninu wọn ni L.A. Primary School, Alágbọn ati L.A Primary School, to wa ni Kájọlà; Normadic Primary School, Mágbẹ̀jẹ́, ati bẹẹ bẹẹ lọ.”
A fẹ ki ijọba waa ba wa le Wakili nitori ko fi awa araalu lọkan balẹ.”