Fani-Kayọde n lo sinu APC, lawon eeyan ba ni alailojuti ni

Faith Adebọla

 

 

Latari awuyewuye to gbode kan nigba tawọn eeyan ri minisita feto irinna ọkọ ofurufu tẹlẹ, Oloye Fẹmi Fani-Kayọde, to lọọ ṣepade bonkẹlẹ pẹlu alaga afun-n-ṣọ ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, okunrin naa ni ki i ṣe ohun tawọn eeyan n ro lo ṣẹlẹ o, ipade naa ki i ṣe tori pe oun fẹẹ kuro lẹgbẹ oṣelu PDP rara.

Ori atẹ ayelujara abẹyẹfo rẹ (twitter), lagba oṣelu yii ti sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, o ni loootọ loun atawọn adari APC kan jọọ wọ yara ṣepade, ṣugbọn ọrọ nipa bi nnkan ṣe ri lorileede yii lasiko yii, ki lọna abayọ, awọn ọrọ oṣelu pataki kan lohun tawọn sọ.

B’Oloye Fani-Kayọde ṣe sọrọ ọhun ree: “Lanaa (ọjọ Aje, Mọnde), mo lanfaani lati ṣepade pataki kan pẹlu Alaga apapọ ẹgbẹ APC, Gomina Mai Buni ti ipinlẹ Yobe, ati Gomina Yahaya Bello lati ipinlẹ Kogi. A sọrọ lori bi nnkan ṣe ri lorileede yii lọwọlọwọ yii, awọn ọrọ nipa ijọba apapọ, awọn ẹgbẹ oṣelu ati ọna abayọ sawọn iṣoro wa.

“Ṣe ẹ mọ pe aburu kan to doju kọ wa bayii ni ti ewu pe ogun abẹle le bẹ silẹ lorileede wa. Lai ka ti iyatọ to wa laarin wa si, gẹgẹ bii agbalagba ati alẹnulọrọ, gbogbo wa gbọdọ jogun-o-mi lasiko yii, ka si yee paroko ogun.

“Ko sọgbọn ẹ, awọn eeyan ti wọn o gba tara wọn ṣi maa n lajọsọ lẹẹkọọkan lori awọn ọrọ pataki to ṣe koko, idi ipade naa si niyẹn. Ijiroro naa ko si mọ sibẹ o, a ṣi lajọsọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu mi-in naa, tori ọrọ to wa nilẹ yii, eeyan gbogbo gba ọgbọn kun ọgbọn ni, inu mi si dun pe wọn pe mi si i. Ki Ọlọrun ran orileede wa lọwọ, ko si dari gbogbo wa.”

Sugbon ọgọọrọ awọn to fesi si alaye ti Oloye Fani-Kayọde ṣe yii ni alailojuti eda kan ni okunrin omo bibi Ileefe naa to ba je pe loooto lo tun n pada lo sinu egbe APC to ti bu daadaa. Awon eeyan naa ni alaye rẹ ko sọ oju abẹ nikoo to, wọn ni ko sọrọ soke, ṣe o n lọ sẹgbẹ APC ni tabi bẹẹ kọ, iyẹn lawon fẹẹ mọ. Wọn tun beere pe ṣe loootọ lawọn gomina PDP kan ti wọn o fẹẹ foju han wa nipade naa.

Ọgbẹni Ṣina tilẹ kọ ọ sibẹ pe: Ẹgbọn, ẹ ṣe bii ọkunrin, e yee sọrọ lowe lowe. Ṣe ẹ n bẹbẹ lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC ni abi bawo?

Opo eeyan lo ti n so pe ogun ti okunrin naa you je lo n wa kiri.

Leave a Reply