Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Ni fẹẹrẹ Ọjọbọ, ọjọ kọkanla, oṣu keji yii, lawọn Fulani ti awọn ara Yewa fẹẹ le kuro lagbegbe wọn tun gbinaya. Niṣe ni wọn dena de àwọn ara abule Owode-Ketu, wọn si yinbọn paayan meji. Bo tilẹ jẹ pe awọn mi-in sọ pe eeyan mẹfa ni wọn pa.
Ni gbogbo asiko ti a n kọ iroyin yii, titipa lawọn ileewe, ọja, ileeṣẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ wa lawọn agbegbe bii Owode -Ketu-Ijoun, Tata, niṣe ni kaluku n pe ara wọn lori foonu pe ṣe Fulani ko ti i dọdọ wọn.
Ibọn ati ada ni ALAROYE gbọ pe aawọn Fulani to pa awọn baale ile meji ni fẹẹrẹ yii lo, bi wọn ṣe yinbọn fún wọn ni wọn tun ṣa wọn ladaa, bi wọn si ti kúrò l’Owode bayii, wọn ni wọn kọri si ona Eggua ni.
Wọn ni awọn kan gba ọna Igan Alade, awọn kan si gba ọna Igbogila lọ ninu wọn. Ijọba ibilẹ Ariwa Yewa lawọn ilu yii wa, nipinlẹ Ogun.
Nigba to n sọrọ nipa iṣẹlẹ yii, Eselu ti Iselu, Ọba Akintunde Akinyẹmi, ṣalaye pe awọn ko ti i le sọ iye eeyan tawọn Fulani wọnyi pa, nitori awọn tawọn ri oku wọn ṣi ree, awọn eeyan ti ẹnikẹni ko ti i mọ bi wọn ku tabi wọn ye ṣi wa nibẹ.
Kábíyèsí sọ pe Iselu paapaa ko ni ifọkanbalẹ lasiko yii, nitori awọn Fulani to n rin kiri yii ko fi agbegbe awọn silẹ.
Eselu sọ pe oun ti paṣẹ pe ko si oorun mọ fawọn ọkunrin Iselu, ki kaluku bẹrẹ si i ṣe fijilante, ki wọn ko awọn obinrin wọn lọ si Ọja Ọdan, titi ti wahala yii yoo fi mọwọ duro.
Awọn ọlọpaa Eggua ni wọn waa gbe oku meji to wa nilẹ lọwọ idaji naa lọ.
Nigba tọrọ ti ri bayii, bíi pe ilu ti dahoro ni, eyi ni ko jẹ ka ri ẹbi awọn to doloogbe ba sọrọ.