Stephen Ajagbe, Ilorin
Baale ile kan, Usman Abdulkareem, toun pẹlu ọrẹ rẹ to n ṣiṣẹ babalawo, Fatai Adisa, lẹdi apo pọ lati ji iyawo rẹ, Muminat gbe, nile-ẹjọ Magisreeti kan to wa niluu Ilọrin paṣẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, pe ki wọn wa lahaamọ ọgba ẹwọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa to wọ awọn afurasi naa wa sile-ẹjọ ni awọn mejeeji jọ gbimọ-pọ lati huwa ọdaran nipa jiji obinrin naa gbe, ki wọn le fi ṣoogun owo.
Aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa, Abubakar Issa, ṣalaye pe ọkọ Muminat lo pe e lori foonu ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ, to si ni ko waa pade oun nile ọrẹ oun (Adisa).
O ni iwadii awọn fi han pe babalawo ni Adisa, o si maa n lo ẹya ara eeyan lati fi ṣe oogun owo fawọn to ba nifẹẹ si i.
Issa rọ ile-ẹjọ lati sun igbẹjọ naa siwaju ki ileeṣẹ ọlọpaa le pari iwadii wọn.
Awọn olujẹjọ naa lawọn ko jẹbi ẹsun ọhun nigba tile-ẹjọ ka a si wọn leti.
Adajọ Afusat Alegẹ paṣẹ pe ki wọn maa ko wọn lọ satimọle ọgba ẹwọn Oke-Kura, o sun ẹjo naa si ọjọ kẹrinlelogun, oṣu keji, ọdun yii.