“Ti awọn Fulani darandaran ko ba fẹẹ ko si wahala awa ọmọ ẹgbẹ OPC, anfaani nla ni yoo jẹ fun wọn ti wọn ba le fi gbogbo ilẹ Yoruba silẹ, nitori ohun to foju han bayii ni pe bi wọn ṣe le wọn kuro nipinlẹ Ọyọ, ipinlẹ Ogun ni wọn ko ara wọn wa, ti wọn fẹẹ maa faye ni awọn eeyan lara.”
Aarẹ Ọnakakanfo, Iba Gani Adams, lo ṣe bayii sọrọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, lori bi awọn Fulani darndaran ṣe da ẹran wọnu ile Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka lagbegbe Ijẹgba, laipẹ yii.
Ninu ọrọ ẹ naa lo tun ti sọ pe ẹgbẹ OPC ko ni i fọwọ yẹpẹrẹ mu awọn eeyan yii lori bi wọn ti ṣe fẹẹ maa ko idaamu ba awọn eeyan nilẹ Yoruba.
Ninu atẹjade ti Kẹhinde Aderemi, oluranlọwọ fun Aarẹ Ọnakakanfo nipa eto iroyin, fi sita ni Gani Adams ti sọ pe ọna ti awọn darandaran yii gba ko maaluu wọle Ọjọgbọn yii, bii ẹni gbiyanju lati fi ẹmi Wọle Ṣoyinka wewu ni.
O ni ohun to foju han bayii ni pe awọn janduku to wa ninu awọn darandaran yii ti kuro ni Ibarapa, ipinlẹ Ogun ni wọn wa, paapaa lagbegbe Yewa.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe ohun iyalẹnu lo n jẹ lori bi Aarẹ Muhammadu Buhari ko ṣe gbe igbesẹ to yẹ lori awọn janduku darandaran ti wọn n ṣe ẹmi awọn awọn eeyan lofo lasiko yii.
Aarẹ Ọnakakanfo ti waa rọ awọn gomina ilẹ Yoruba lati ṣeto iranwọ to yẹ fun awọn ọmọ ẹgbẹ OPC, awọn Amọtẹkun atawọn fijilante, ki eto aabo le fẹsẹ rinlẹ daadaa nilẹ Yoruba.
O ni, “OPC ṣetan lati fọwọsowopọ pẹlu awọn gomina ilẹ Yoruba lori ọrọ aabo to delẹ yii lati gbogun ti awọn darandaran ti wọn ti di ijangbọn nla si ilẹ Yoruba.
Siwaju si i, Gani Adams tun gba awọn gomina niyanju lati tubọ ro awọn Amọtẹkun lagbara lati maa ṣọ awọn aafin ọba, ile awọn gbajumọ nla laarin ilu, awọn abule atawọn igberiko pẹlu gbogbo ibi to ba yẹ, ki aabo to peye le wa fun ẹmi awọn eeyan ati dukia wọn.