Ọpọlọpọ ile ati ṣọọbu wa lawọn Hausa dana sun lọja  Ṣáṣá, n’Ibadan-Adelabu 

*Ọ̀pọ ile ati ṣọ́ọ̀bù Yoruba lawọn Hausa dana sun

Ọlawale Ajao, Ibadan

O kere tan, eeyan mẹrin lo ku, ti ọpọlọpọ ohun irinṣẹ ati ọkẹ àìmọye dukia sí ṣegbe, sinu laasigbo to waye laarin awọn Hausa ati Yoruba laduugbo Ṣáṣá, n’Ibadan, lọjọ Ẹtì, Furaidee, to kọja.

Oku eeyan meji ti wọn dana sun si ẹgbẹ títì ọna Ọ̀jọ́ọ̀ sí Mọ́níyà, ni Ṣáṣá, n’Ibadan, pẹlu ọkada meji, ṣi n jona lọwọ titi ti akọroyin wa fi kuro níbẹ ni nnkan bíi aago mẹfa irọlẹ ọjọ Ẹti ọ̀hún.

Niṣe láwọn ti ori ko yọ lọwọ òfò dukia sáré lọọ ṣáátà ọkọ lati ko gbogbo ẹrù to wà nínú ṣoọbu wọn. Ẹ̀rù ìjàmbá ina nikan kọ lo n ba wọn, bi ko ṣe nítorí fifọ ti wọn láwọn Hausa wọnyi n fọ́ awọn ṣọọbu ti wọn ba mọ pé wọn lọ́jà ninu daadaa, ti wọn sì n ji awọn ẹru to wa nibẹ ko. Bi wọn sì ṣe jale láwọn ṣọ́ọ̀bù ti wọn dana sun naa ree ki wọn tóo ṣáná sí ahoro ṣọ́ọ̀bù.

 

Ṣáṣá jẹ ọkan ninu awọn abúlé ilẹ̀ Ibadan, ṣugbọn to ti wa ninu igboro ilu naa bayii latari bi Ibadan ṣe n gbòòrò sí í lojoojumọ. Ibẹ sì lọja ti ata ati ohun eelo ọbẹ pọ sí ju lọ wa jakejado ipinlẹ Ọyọ.

Nigba ti yóò fi di aago mẹfa irọlẹ ọjọ náà, gbogbo ọmọ Yorùbá to wa ninu igboro Ṣáṣá ni wọn ti fi ile wọn silẹ. Gbogbo wọn sa àsálà fún ẹmí wọn nitori ti awọn Hausa ti dana sun ile ati ṣọọbu ti púpọ ninu wọn ti n taja.

 

Làásìgbò ọhun la gbọ pe o bẹ silẹ lẹyin ti Hausa kan to jẹ alábàárù lù ọmọ Yorùbá kan to n jẹ Adéọlá Sakirudeen lóògùn, ti ìyẹn sí tibẹ dagbere faye.

Lati irọlẹ Ọjọbọ, Tọ́sìdeè, leefin ija ọhun ti n rú túú bọ nigba ti gbólóhùn asọ kan wáyé láàrin aláboyún kan pẹlu ọkunrin Hausa alábàárù kan to ba a gbẹ́rù.

Gẹgẹ bi awakọ kan to n na ọna Ṣáṣá ṣe fìdí ẹ mulẹ fakọroyin wa “Obinrin oloyun kan ni Hausa alábàárù yẹn n ba já pe o da omi sí oun lára. Obinrin yẹn sọ pé oun ko da omi sí i lara, ati pe ṣebi oun naa ri i pe oun fẹẹ da omi ko too mọ-ọn mọ sáré sí ẹnu omi bíi ẹni to n wa wahala.

 

“Ọrọ yii ni wọn n fa mọ ara wọn lọwọ ti ọkunrin Yoruba kan (Sakirudeen) fi n ba Hausa wí, pe ṣo waa fẹẹ máa ná aláboyún ní. Ọmọ Yorùbá yẹn ko sọ jù bẹẹ lọ ti Hausa yẹn fi nà a lóògùn.”

Olugbe inu Ṣáṣá kan Alhaji Ibrahim Adelabu, ẹni to fara gbá nínú laasigbo yii ṣalaye pe “Bi awọn Hausa ṣe gbọ pe ẹni ti ọkan ninu awọn na lóògùn ti ku ní wọn ti mura ìjà, wọn ro pe awọn Yorùbá máa gbẹsan.

“Lati oru ọjọ Tọsidee yẹn mọju aarọ Jimọ ni wọn ti n ko àdá, idà atawọn nnkan ìjà oloro kaakiri inu Ṣáṣá, tí wọn sì bẹrẹ sí í ṣe àwọn eeyan leṣe, ti wọn tun n dana sun ile awọn Yorùbá kaakiri ni.

“Ṣadeede ni mo ri wọn nile témi naa ti wọn waa dana sunle mi.

Leave a Reply