Faith Adebọla
Pẹlu bi ijọba atawọn olugbe agbegbe Ibarapa ṣe n wa gbogbo ọna lati fopin si eto aabo to mẹhẹ, ijinigbe, ipaniyan ati biba oko oloko jẹ to ti n waye latọwọ awọn Fulani darandaran, eto ibura ati imulẹ kan ti n lọ lọwọ bayii laarin awọn olugbe ilu Igangan, nijọba ibilẹ Ariwa Ibarapa.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, awọn olori ilu naa, eyi ti Kabiyesi Aṣigangan tilu Igangan, Ọba Lasisi Adeoye ṣaaju fun, lo gbe eto naa kalẹ.
Igbakeji Kọmandanti ikọ ẹṣọ alaabo Amọtẹkun, ẹka ti Ariwa Ibarapa, Kọmureedi Ishau Adejare, sọ fakọroyin wa lori aago pe iwadii fihan pe awọn ọmọ oniluu kan wa ti wọn n gbọbọde, ti wọn n huwa agbẹyin-bẹbọjẹ, wọn n ṣe wọlewọde pẹlu awọn afurasi ọdaran Fulani naa, eyi lo si mu ki Seriki Fulani, Abdulkadir Salihu, raaye gbilẹ.
“Lara atilẹyin tilu ṣe fun eto aabo ijọba ni gbogbo ile kọọkan, araalu kọọkan to ba ti tojuubọ, atọkunrin atobinrin lati agboole si agboole lo gbọdọ mulẹ niwaju awọn alalẹ, pe oun o ni i dalẹ ilu, ati pe toun ba ṣe bẹẹ, ki awọn alalẹ da sẹria foun.
Kaakiri ile ni wọn n lọ gẹgẹ bi ọkunrin naa ṣe sọ, ti awọn olori ile yii si n fi ohun imulẹ yii ṣebura pe aọn ko ni i gbabọde fun ilu naa.
“Ni ti awọn ọmọ ilu to wa lẹyin odi, tabi ti ko si nile lasiko yii, gbogbo wọn pata lawọn araale wọn maa darukọ wọn niwaju awọn alalẹ. Eto naa ko yọ ẹnikẹni silẹ, ile kabiesi wa gan-an lo ti bẹrẹ, o si maa kari pata.”
O lanfaani mi-in to wa ninu igbesẹ naa, yatọ si pe yoo mu ko ṣoro fun ọmọ ilu kan lati ṣonigbọwo fun ajoji tabi awọn ọdaran ti wọn fẹẹ ṣe ṣuta ni pe, idajọ awọn alalẹ ki i ṣe ọrọ ile-ẹjọ tabi eyi ti wọn maa dẹbi ẹ ru ẹnikẹni.
Ni bayii, Ishau ni ko si ẹyọ Fulani darandaran kan laarin ilu Igangan mọ, gbogbo wọn ti kuro niluu, ati pe awọn agbẹ ti n lọ soko diẹdiẹ, bo tilẹ jẹ pe ibẹru ati ifura ṣi wa lọkan awọn araalu.
O lawọn ire oko ti wọlu diẹdiẹ ju tatẹyinwa lọ, awọn eeyan si ti n pọ lawọn ọja wọn tori awọn ero oko ati abule diẹ ti n waa na ọja, ẹṣọ alaabo Amọtẹkun ṣi n rin kaakiri aarin ilu ati lawọn ọna marosẹ lagbegbe naa, bẹẹ lawọn ẹṣọ OPC kun wọn lọwọ.