Faith Adebọla, Eko
Ohun ti aṣẹwo kan ro kọ lo ba pade pẹlu bi kọsitọma ọran to wọle tọ ọ lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ṣe fabọn yọ si i. Peter Arinọla ni alejo ọran ọhun, oun lo fẹẹ fi tipa ṣe ‘kinni’ fun aṣẹwo ni Surulere.
Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, wọn ni afurasi ọdaran yii lọọ ba aṣẹwo ti wọn forukọ bo laṣiiri naa, tawọn mejeeji si dunaa-dura owo to maa gba lati ba ara wọn laṣepọ.
Ṣugbọn ìná ò wọ̀ laarin wọn, iye ti aṣẹwo loun fẹẹ gba ju iye ti Peter loun maa san lọ, bẹẹ Peter loun o fẹẹ ṣere oniṣẹẹju perete, alaṣemọju loun fẹ, n laṣẹwo ba ni ko wa ọlọja tiẹ siwaju.
Ṣugbọn ti Peter yii fa ija, koda, o fa ju ija lọ, wọn ni ṣe lọkunrin yii fa ibọn pompo yọ ninu apo ẹ, o loun maa yin in mọ aṣẹwo naa to ba kọ ti ko foun laaye lati gbe e mọju.
Alukoro ọlọpaa Eko to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ni aṣewo naa ko ṣe meni ṣe meji, niṣe lo figbe ta gidigidi, ki Peter si too tọju ibọn sapo pada, awọn ero ayika ile aṣẹwo ti pe le wọn lori, ni wọn ba gba afurasi ọdaran yii mu pẹlu ibọn ọwọ ẹ, wọn ko lo ba di agọ ọlọpaa Surulere.
Ọlọpaa gba ibọn Revolver ọwọ ẹ pẹlu ọta ibọn ti wọn ko ti i yin marun-un lapo Peter, igba ti wọn si wadii ọrọ lẹnu rẹ, wọn lo jẹwọ pe adigunjale loun, ṣugbọn oun kọ loun ni ibọn yii, ẹnikan tawọn jọ n ṣiṣẹ adigunjale lo ni in, bo tilẹ jẹ pe ko darukọ ẹ.
Ṣa, wọn ti sọ jagunlabi sahaamọ awọn ọtẹlẹmuyẹ ni Panti, Yaba, fun iwadii, ki wọn too gbe e lọ siwaju adajọ.