Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ode ro lagbegbe Ṣagamu lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keji yii, nigba tawọn ọlọkada kan bẹrẹ si i fẹhonu han, ti wọn si gba ọfiisi ijọba ibilẹ to wa loju ọna Ayepe lọ lati ta ko bi ọkan ninu wọn ṣe fori gbalẹ, to si ku lẹsẹkẹsẹ, nibi to ti n sa fun agbofinro to fẹẹ mu un.
Ohun ti awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ ni pe ikọ to maa n mu wọn ti ijọba ibilẹ Ṣagamu ran niṣẹ lo fẹẹ mu ọlọkada to doloogbe yii, nitori ọkunrin Hausa naa ta ko ofin irinna. Ṣugbọn ọlọkada naa ko fẹ ki agbofinro ọhun mu oun, n lo ba n dọgbọn ati sa mọ ọn lọwọ.
Nibi to ti n gbiyanju ati bọ lọwọ ẹni to fẹẹ mu un naa lo ti ṣubu pẹlu ọkada, ori lo fi gbalẹ, ẹsẹkẹsẹ lo si dagbere faye bi wọn ṣe wi.
Iku ọkunrin naa lo bi awọn eeyan rẹ ninu, ni wọn ba bẹrẹ si i fa wahala, wọn di oju ọna, wọn si ba awọn ọkọ pẹlu awọn dukia mi-in jẹ pẹlu ki wọn too ko ifẹhonu han naa lọ si sẹkiteeria ijọba ibilẹ to wa ni Ayepe. Koda, niṣe lawọn ọlọja n sare ti ṣọọbu, ti kaluku n sa asala fun ẹmi wọn.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, Abimbọla Oyeyẹmi, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni awọn ti kapa wahala naa, ohun gbogbo si ti pada si bo ṣe wa tẹlẹ lagbegbe naa, ko si wahala mọ rara.