Aarẹ Muhamadu Buhari yoo lọ si orilẹ-ede Mali loni-in yii. Ipade pataki kan lo n ba lọ. Wọn n ja ni orilẹ-ede naa ni, awọn ajijagbara ati awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu mi-in n ba Aarẹ ibẹ, Ibrahim Keita, ja ija ajadiju, wọn ni afi ko fi ipo to wa silẹ, bi bẹẹ kọ ko ni i si alaafia lorilẹ-ede Mali. Ọrọ oṣelu naa lo si fa ija wọn o, ọrọ a-dibo a-o-dibo yii naa ni, n lo di ohun ti wọn n pa ara wọn si, tawọn agbaye gbogbo si n bẹru pe ọrọ naa le dogun.
Ki ọrọ yii ma di wahala ni awọn ajọ orilẹ-ede Iwọ-oorun Africa ti wọn n pe ni ECOWAS ṣe gbe igbimọ kan dide pe ki wọn ba wọn pari ija naa ni Mali. Ninu igbimọ yii, wọn yan aarẹ ilẹ wa tẹlẹ, Ọmọwe Goodluck Jonathan, lati jẹ apaṣẹ pataki nibẹ, oun naa lo si pada waa ṣalaye ohun gbogbo to n lọ ati ibi ti ọrọ de duro fun Buhari nijẹta.
Alaye ti Jonathan ṣe pe awọn olori oirlẹ-ede Ghana, Ivory Coast, Niger ati Senegal yoo wa ni Bamako ti i ṣe olu ilu naa loni-in yii, lati jokoo papọ lori ọrọ yii lo mu Aarẹ Buhari naa sọ pe ouon yoo tẹ le Jonathan lọ. Ohun to jẹ awọn olori ECOWAS yii logun ni bi ọrọ Mali yii ko ṣe ni i le ju bayii lọ, ti ko si tun ni i di ogun ti apa ko tun ni i ka mọ.