Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọjọbọ, Tọsidee, nileeṣẹ ọlọpaa wọ awọn olufẹhonu han mẹfa tọwọ tẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, fun didi oju titi ati ṣiṣe idiwọ fawọn araalu to n ṣiṣẹ oojọ wọn lasiko ti wọn n fẹdun ọkan wọn han, lọ sile-ẹjọ Magisreeti tilu Ilọrin.
Awọn olujẹjọ naa ni; Isiaka Toyin to n gbe agbegbe Alanamu, Mohammad Solihu Ọlayinka, to n gbe lagboole Owonwami, l’Oke-Suna, Salaudeen Abubakar lati agboole Oke-Ose, l’Oke-Suna, Ibrahim Alabi, to n gbe ni Federal Housing Estate, Ilọrin, Adewale Abdulazeez, to n gbe ni Ganiki phase ll, ni Sango, ati Aransiọla Olubukun, ti Ga’a Akanbi.
Lara ẹsun ti wọn tun fi kan wọn ni aigbọran si aṣẹ ijọba, igbimọ-pọ lati huwa ọdaran ati dida alaafia ilu ru.
Agbẹjọro ijọba, Insipẹkitọ Adewumi Johnson, rọ ile-ẹjọ lati ma gba oniduuro wọn, nitori pe o le ṣe akoba fun iwadii to n lọ lọwọ.
Ṣugbọn agbẹjọro awọn olujẹjọ naa,
Abdullahi Akewuṣọla, bẹ ile-ẹjọ fun beeli wọn, o ni ẹsun ti wọn fi kan wọn ki i ṣe ẹsun ọdaran rara, fun idi eyi ofin faaye beeli gba wọn.
O ṣeleri pe wọn ko ni i ṣi anfaani naa lo bi ile-ẹjọ ba gba oniduuro wọn.
Adajọ A.A Abioye gba beeli wọn pẹlu ẹgbẹrun lọ́nà igba naira ati oniduuro meji to n gbe lagbegbe kootu naa.
O ni ọkan lara oniduuro naa gbọdọ jẹ ibatan awọn olujẹjọ ọhun, bẹẹ si ni ekeji gbọdọ jẹ oṣiṣẹ ijọba nipinlẹ Kwara.
Adajọ sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ọdun yii.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, lọwọ ọlọpaa tẹ wọn fẹsun titapa si ofin Covid-19.
Labẹ asia awọn olukọ tijọba ana gba siṣẹ, ṣugbọn tijọba to wa lori ipo juwe ile fun, eyi ti wọn n pe ni (Sunset Teachers), ni awọn olufẹhonu han ọ̀hún to jokoo soju ọna Ahmadu Bello, ti wọn si di irinna ọkọ loju ọna naa lọwọ.
Ohun tijọba to wa nipo bayii sọ ni pe ilana tijọba ana fi gba wọn sẹnu iṣẹ lodi sofin, ati pe ọpọlọpọ lara wọn ni ko ni iwe-ẹri iṣẹ olukọ ti wọn gba wọn si, fun idi eyi, ki wọn gba ile wọn lọ.
Lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin lawọn eeyan ọhun ti n fapa janu, wọn fẹdun ọkan wọn sijọba lori bo ṣe gbaṣẹ lọwọ wọn.
Bo tilẹ jẹ pe awọn agbofinro, paapaa ọlọpaa, ko da wọn lọwọ kọ latigba ti wọn ti n fẹhonu wọn han wọọrọwọ, ṣugbọn igbesẹ ti wọn gbe l’Ojọruu lati ṣediwọ fawọn araalu to n ṣiṣẹ oojo wọn lọna ti wọn ti pa naa lo mu kawọn ọlọpaa lọọ ko lara wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, ni ẹtọ gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ni lati fẹhonu han lalaafia, ṣugbọn iru ifẹhonu han bẹẹ ko gbọdọ jẹ idiwọ fun araalu.
O ni Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Mohammed Lawal Bagega, fi da araalu loju pe aabo to peye wa fun dukia ati ẹmi wọn. O ṣekilọ fawọn to ba fẹẹ tẹ ofin loju lati jawọ kia, bi bẹẹ kọ wọn yoo kan idin ninu iyọ.