Oloye Fẹmi Fani Kayọde ti sọ pe ko sohun to buru ninu ki awọn ọmọ Naijiria yooku naa maa lo ibọn lati fi daabo bo ara wọn niwọn igba ti wọn ti sọ pe awọn Fulani darandaran lẹtọọ lati maa gbe ibọn kiri.
Ọjọbo, Tọsidee, ni Oloye Fẹmi Fani-Kayọde sọrọ yii nigba to lọọ ṣabẹwo si Oloye Sunday Adeyẹmọ, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho, niluu Ibadan.
Ọkunrin Amofin ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP yii sọ pe awọn ọmọ Naijiria yooku naa lẹtọọ lati maa lo ibọn AK-47 niwọn igba ti awọn eeyan kan ti n sọ pe bi awọn Fulani darandaran ṣe n lo o fi daabo bo ara wọn yẹn ko si aburu nibẹ rara.
Fani-Kayode sọ pe ọna kan pataki ti a le gba fi gbogun ti eto aabo to mẹhẹ lorilẹ-ede yii ni ki ijọba Naijiria jara mọ ojuṣe ẹ lori wahala to delẹ yii.
Bakan naa lo sọ pe ọna mi-in ti awọn eeyan orilẹ-ede yii tun le gba fi bọ ni ki ijọba fun kaluku laṣẹ lati maa lo ibọn fun idaabo bo ẹmi ara wọn ati dukia wọn.
Ṣaaju asiko yii ni Minisita fun ero aabo, Ọgagun Bashir Magashi, ti rọ ijọba ko fun awọn eeyan lanfaani lati maa lo ibọn fi ṣọ ẹmi ara wọn ati dukia, paapaa lọwọ awọn janduku ajinigbe atawọn oniṣẹ ibi mi-in.
Fani sọ pe, “Gbogbo wa naa la gbọ ọ nigba ti gomina ipinlẹ Bauchi sọ ọ laipẹ yii pe ibọn ti awọn Fulani darandaran n ko kiri ko lodi sofin rara niwọn igba ti ijọba ko ti le pese aabo to yẹ fun wọn. Emi ko fara mọ eyi rara bo tilẹ jẹ pe ero tiẹ niyẹn, sugbọn ti a ba ni ka tẹle ohun to sọ yẹn, anfaani naa ni yoo jẹ fun awọn agbẹ naa lati maa lo ibọn niwọn igba ti awọn Fulani naa ba ti n lo o. Ti Fulani ba n lo ibọn fi daabo bo maaluu, ko sohun to ni ki agbẹ naa ma daabo bo ire oko tiẹ naa lọwọ Fulani ti wọn n wọle paayan kiri.”
“Awọn eeyan ilẹ America naa niru anfaani yii, ka ni awọn eeyan wa naa ti n lo ibọn ni, iru wahala tawọn Fulani n ko ba wọn yii ko ni i waye. Wahala to n ṣẹlẹ kaakiri yii ki i ṣe nilẹ Yoruba nikan, bẹẹ lo ṣe n lọ ni ilẹ Hausa pẹlu. Fun idi eyi, ijọba ni lati dide si ojuṣe wọn, ki wọn si pese aabo to yẹ, nitori ẹ la ṣe n sanwo fun wọn.”
Bakan naa lo fi kun un pe ki i ṣe pe Sunday Igboho kan n kọ lu awọn Fulani darandaran kiri bi ko ṣe awọn janduku kan laarin wọn.
Fani Kayọde loun fara mọ igbesẹ Sunday Igboho lori bo ṣe n ja fun awọn eeyan ẹ nilẹ Yoruba, ati pe oju ti oun fi wo ọkunrin aṣaaju ogun yii, eeyan kan to ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu ẹnikẹni to ba n wa alaafia nilẹ Yoruba ni.
Ninu ọrọ Sunday Igboho loun ti sọ pe oun fara mọ ohun ti Fani Kayọde sọ, nitori oun ko ni i gba janduku darandaran kankan laaye lati ba ilẹ Yoruba jẹ.