Faith Adebọla
Eekan oloṣelu ilu Eko to tun jẹ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC lapaapọ, Bọla Ahmed Tinubu, ti fidi ẹ mulẹ pe loootọ lasiko yii o fara rọ fun orileede wa, o ni Naijiria wa ninu yanpọnyanrin gidi, ṣugbọn adura ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki ogun ṣẹlẹ, tori ogun ki i bimọ ire.
Tinubu sọrọ yii lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nibi akanṣe adura to waye ni iranti Oloogbe Lateef Jakande, ti wọn ṣe nile oloogbe naa lagbegbe Ilupeju, l’Ekoo.
Tinubu, toun naa ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko bii ti Jakande sọ pe wahala to n ṣẹlẹ lorileede wa lasiko yii ko fara sin pẹlu bawọn janduku, afẹmiṣofo ati agbebọn ṣe gbode kan, ti eto aabo si dẹnu kọlẹ, eyi to fihan pe ara ọ rọ okun, ara o rọ adiẹ rara, ṣugbọn adura oun ni pe ki Ọlọrun to pese ọpọ awọn nnkan amuṣọrọ rẹpẹtẹ fun Naijiria, ko daabo ẹ bo wa, ko ma jẹ ki ṣangba fọ lorileede yii.
O ni awọn to ti ri ohun ti ogun n da silẹ ri, bi ogun ṣe maa n fa ẹlẹyamẹya ati ija ẹsin, iru awọn ẹni bẹẹ ko jẹ gbadura pe ki ogun tun ṣẹlẹ.
“Niṣe ni ka maa gbadura k’Ọlọrun tubọ fi ero rere si wa lọkan, ka le mu alaafia ati itẹsiwaju ba ilẹ wa. Ọlọrun lo maa dajọ awọn to n fa wa sẹyin, aa si fẹsẹ wa le ọna rere. O ku sọwọ emi, iwọ, ati gbogbo wa.”
Aṣiwaju Bọla Tinubu tun fi kun ọrọ rẹ pe oun o le gbagbe ajọṣe gidi toun ni pẹlu Oloogbe Jakande, bo ṣe jẹ ile rẹ loun ti bẹrẹ irinajo oṣelu oun, ile naa loun ti ṣe ọmọ-ọwọ lagbo oṣelu.
“Adanu nla ni iku Jakande jẹ fun ipinlẹ Eko ati Naijiria. Ti mo ba ni ki n kọwe nipa Jakande, ma a kọwe lọ bii ilẹ bii ẹni ni, tori mo ṣoriire gidi, mo lanfaani lati mọ baba naa lati kekere mi.
“Adura mi ni pe k’Ọlọrun tun fun Eko ati Naijiria lawọn aṣaaju rere to maa jẹ olootọ, ati ẹni to n nawo sọna to tọ, bii ti baba daadaa to ku yii.