Florence Babaṣọla, Osogbo
Ifamoyegun Rẹmi, ẹni ọdun mejidinlogoji, ni aṣoju ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti taari wa si kootu Majisreeti ilu Oṣogbo lori ẹsun ole jija.
Ileeṣẹ Mobil Oil Nigeria Plc, to wa ni Oke-fia, niluu Oṣogbo, la gbọ pe Rẹmi ti n ṣiṣẹ lati ọdun 2016, latigba naa lo si ti rọra n ji wọn ni ọili ẹnijinni (engine oil) wẹrẹwẹrẹ.
Ọjọ kọkanla, oṣu kẹfa, ti a wa yii lakara tu sepo fun Rẹmi, aṣiri tu, wọn fa a le awọn agbofinro lọwọ, lẹyin ti wọn gba ọrọ lẹnu ẹ ni wọn gbe e wa si kootu.
Inspekitọ Kayọde Adeoye sọ ni kootu pe latigba ti Rẹmi ti de ile-epo naa lo ti bẹrẹ iwa ole, inu yara ikẹrusi lo ti lọ maa n ji ọili, ti yoo si dọgbọn ta a.
Adeoye ni to ba ti ji ọili bu tan ni yoo rọ omi sinu kẹẹgi kawọn oṣiṣẹ yooku ma baa tete fura pe ko si nnkan kan ninu kẹẹgi mọ.
O ni owo ọili ẹnjinni ti Rẹmi ti ji ti to ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta o din diẹ Naira (#469,000.00), eyi to si jẹ ẹṣẹ to nijiya labẹ ofin kẹrinlelogun iwa ọdaran nipinlẹ Ọṣun.
Nigba ti wọn n beere boya o jẹbi, Rẹmi ni oun jẹbi ẹsun naa, ṣugbọn kile-ẹjọ ṣiju aanu wo oun. O ni koun le rowo tọju iya oun pẹlu iyawo oun lo sun oun dedii ole jija, nitori owo-osu toun n gba ko le gbọ gbogbo bukaata naa.
Lẹyin eyi ni Adajọ Risikat Ọlayẹmi sọ pe ki Rẹmi lọọ fi aṣọ penpe roko ọba fun oṣu meje gbako lai fi aaye faini silẹ fun un. Adajọ tun paṣẹ fun un lati san ẹgbẹrun lọna irinwo Naira fun olupẹjọ.