Baba ti wọn mu nitori wọn lọmọ ẹ n ja n’Ibadan ti ku sọdọ awọn ọlọpaa o

Ijẹsan-an lawọn ọlọpaa ti mu un, ni Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja. Wọn mu baba naa, Kẹhinde Ọmọtọṣọ ti awọn ọrẹ rẹ n pe ni Akéde, ati ọmọ rẹ kan to n jẹ Jẹlili. Ẹsun ti wọn fi kan an ni pe ọmọ rẹ mi-in to n jẹ Kabiru ja pẹlu awọn kan, wọn si fẹẹ mu Kabiru, igba ti wọn ko si ri Kabiru mu, ni wọn ba mu baba yii ati jẹlili, ni wọn ba lọọ ti wọn mọle ni Ọgba ọlọpaa Iyaganku. Ni bayii, Kehinde ti ku mọ awọn ọlọpaa Iyaganku lọwọ o.

“Eyi to ṣẹlẹ yii, yoo fọn awọn ọlọpaa níkun: wọn yoo rojọ ẹnu wọn yoo fẹrẹ bo.” Bẹẹ ni Akin Fadeyi, ọga ileeṣẹ Ajafẹtọọ-ọmọniyan kan, Akin Fadeyi Foundation wi. O ni iwa ika gbaa ree lati ọdọ awọn ọlọpaa, nitori jẹjẹ ni Kẹhinde n taja rẹ ni Gbagi niluu Ibadan, ko si ba ẹni kan ja, ko si ṣe kinni kan to lodi sofin. Afi bi awọn ọ̀ọpaa ti lọ sile rẹ ti wọn ni awọn n wa Kabiru ọmọ rẹ, pe iyen ba awọn kan ja. Wọn ko si ba Kabiru nile, ni wọn ba ni dandan ni ki baba rẹ ati ọmọ rẹ mi-in ti wọn tun ba nibẹ tẹ le awọn. Lati ọjọ naa ni wọn ti ti wọn mọle si Iyaganku, ti wọn ko si jẹ ki awọn ẹbi wọn ri wọn.

Fadeyi ni, “Ọjọ meje ni wọn fi ti Kẹhinde mọle, ti wọn ko jẹ kẹni kan ri i ninu awọn ẹbi rẹ. Laarin alẹ ana si aarọ yii ni wọn ni Kẹhinde ti ku sọdọ wọn. Awọn ẹbi ẹ n sọ pe nitori pe awọn ko lowo, ti awọn ko si leeyan lawọn ọlọpaa ṣe fẹẹ fi iya yii jẹ awọn gbe. Ṣugbọn ki awọn ọlọpaa mọ pe ọrọ naa ko ni ṣee da ewe bo mọlẹ bẹẹ o, yoo la ariwo gidi lọ!”

 

Leave a Reply