Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta
Ọmọ jayejaye ati gbajumọ obinrin ni Mary Maisirat Akerele, n’Idiroko, ipinlẹ Ogun, bẹẹ lawọn eeyan mọ ọn si oniṣowo pẹlu. Ṣugbọn arẹwa obinrin naa ti wa lọgba ẹwọn Ibara bayii, nitori EFCC ti mu un pe o lu jibiti miliọnu marundinlogoji, ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta ati ogun naira (35,520,000).
Adajọ ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ogun ( Kootu Kẹrin) Onidaajọ Abiọdun Akinyẹmi, lo paṣẹ lọjọ Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu keji, pe ki wọn ju Mary ti wọn fẹsun jibiti marun-un kan, sẹwọn titi di ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ti wọn yoo jiroro lori beeli rẹ.
Gẹgẹ bi Agbẹnusọ EFCC , Wilson Uwujaren, ṣe ṣalaye. O ni wahala bẹrẹ si i de ba Mary, ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta, nigba to gba owo yii lọwọ obinrin kan, Alaaja Fausia Ọladọja Abikẹ, pẹlu adehun pe oun yoo ko irẹsi tirela mẹrin fun un lati ileeṣẹ onirẹsi kan to wa ni Bida, nipinlẹ Niger.
Agbẹnusọ EFCC tẹsiwaju pe ṣugbọn kaka ki Mary, ẹni ti orukọ okoowo rẹ n jẹ Goodness of Jesus Global Ventures, ko irẹsi lọ fun Alaaja Fausia to gbowo rẹpẹtẹ lọwọ ẹ, o ni niṣe lo fowo ọhun ṣe faaji ara ẹ, irẹsi kan lo kere ju, ko si tẹ iya to kowo fun un lọwọ.
Ọdun 2018 ni Mary gba owo yii diẹdiẹ lọwọ Alaaja Fausia niluu Abẹokuta gẹgẹ bi agbẹnusọ ṣe wi. Latigba naa ni ko si ko ọja lọ fun Alaaja, bẹẹ ni ko da owo rẹ pada fun un.
Nigba to n fesi, olujẹjọ loun ko jẹbi awọn ẹsun marun-un ti ijọba fi kan oun. Lọọya rẹ, H. A. Omikunle, rọ kootu pe ki wọn fun onibaara oun ni aaye beeli, ko maa ti ile waa jẹjọ. Ṣugbọn lọọya to n ṣoju fun EFCC, Shamsuddeen Bashir, ta ko eyi.
O ni ki Adajọ ma fun Mary ni beeli, nitori wọn ti fun un ri ti ko tẹle awọn ofin to de beeli ti wọn fun un.
Bi Adajọ Akinyẹmi ṣe gbọ eyi lo ni ki wọn maa gbe Mary Akerele lọ sọgba ẹwọn Ibara, ko wa nibẹ titi di ọjọ kẹrin, oṣu kẹta, ti wọn yoo ṣiṣẹ lori beeli to fẹẹ gba.