Florence Babaṣọla
Ọkunrin kan, Teslim Ibitoye, ti rawọ ẹbẹ si igbimọ tijọba ipinlẹ Ọṣun gbe kalẹ lati ṣewadii oniruuru ẹsun awọn araalu ta ko SARS lati paṣẹ funleeṣẹ Ọṣun pe ki wọn gbe oun lọ fun iṣẹ-abẹ loke okun latari ọta-ibọn to wa lara oun latọdun 2017.
Yatọ si tiẹ, Teslim tun beere pe ki awọn ọlọpaa yọnda oku aburo oun ti wọn ti gbe si mọṣuari lati ọdun 2017 tiṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ, ki wọn si san owo gba-ma-bini fun idile na latari wahala ti oju wọn ti ri nipasẹ iṣẹlẹ manigbagbe ọhun.
Teslim ṣalaye pe lọjọ iṣẹlẹ naa, oun ati aburo oun to ti doloogbe lọọ ri mọlẹbi awọn kan torukọ rẹ n jẹ Nureni ni Ẹrin-Ọṣun, o ni awọn ko ba a nile, nigba tawọn pe e lori foonu, o sọ pe kawọn duro.
“Ṣugbọn ni kete ti Nureni de, ko ti i ṣilẹkun ile ti a fi deede gburoo ibọn lakọlakọ, mi o mọ ibi tibọn yẹn ti wa, mo kan mọ pe mo daku lọ rangbọndan ni, bẹẹ ni aburo mi ti ku loju-ẹsẹ ni tiẹ.
“Wọn ko awa mẹtẹẹta sinu mọto, nigba ti afẹfẹ fẹ si mi diẹ ni mo taji, mo ri awọn ọlọpaa yii ti wọn n sọ pe ajinigbe ni wa. Wọn gbe mi lọ si ọsibitu, nigba ti ara mi ya diẹ, wọn ko wa lọ sọdọ kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣogbo, kọmiṣanna si paṣẹ pe ki wọn lọọ tọju wa lọsibitu.
“Ṣugbọn lẹyin ọsẹ diẹ, awọn ọlọpaa yii dọgbọn gbe wa kuro l’Oṣogbo, wọn gbe wa lọ si Abuja, wọn fa mi le Abba Kyari to jẹ adari ikọ awọn ọlọpaa to n ṣewadii abẹnu lọwọ. Bo ṣe ri mi lo paṣẹ pe ki wọn gbe mi lọ si ọsibitu fun itọju to peye, wọn si gbe mi lọ si General Hospital to wa ni Gwagwalada, Abuja.
“Mo kuro lọsibitu lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun 2017, wọn si gbe mi lọ si ọfiisi ileeṣẹ to n gbogun ti iwa ọdaran, State Anti-Robbery Squad (SARS), mo lọ ọsẹ meji nibẹ ki wọn too pada tu mi silẹ.
“A gbe ẹjọ yii lọ sile-ẹjọ giga tilu Oṣogbo, ṣugbọn idajọ ti wọn fun mi nibẹ ko tẹ mi lọrun. Ṣe ni wọn fagi le ẹjọ mi, adajọ ni latari iwa ijinigbe to pọ ju lasiko yẹn lawọn ọlọpaa ṣe mu wa.
“Idi niyi ti mo fi gbe ẹjọ mi wa sibi, a si nireti ninu igbimọ yii. Oku aburo mi ṣi wa lọdọ awọn ọlọpaa latọdun 2017, mo fẹ ki wọn yọnda rẹ fun wa lati lọ sin in.
“Bakan naa ni mo fẹ kigbimọ yii paṣẹ fawọn ọlọpaa lati gbe mi lọ soke-okun fun itọju nitori latigba tiṣẹlẹ yẹn ti ṣẹlẹ ni mo ti n gbe ọta-ibọn awọn ọlọpaa kaakri ni ẹyin mi (spinal cord), gbogbo igbiyanju awọn dokita lati ba mi yọ ọ lo ja si pabo, wọn si ti sọ fun mi pe oke-okun nikan ni wọn ti le ri iṣẹ-abẹ naa ṣe.
“Mo tun fẹ kawọn ọlọpaa san owo gba-ma-binu to nitumọ fun awa mẹtẹẹta nitori idaamu nla niṣẹlẹ naa ti mu ba awọn mọlẹbi wa latọdun mẹrin sẹyin to ti ṣẹlẹ”
Nigba ti olujẹjọ kọkọ fara han niwaju igbimọ, wọn ti sọ pe ki awọn agbẹjọro olujẹjọ ati olupẹjọ lọ si mọṣuari ileewosan ijọba niluu Oṣogbo lati lọọ wo o boya oku aburo Teslim ṣi wa nibẹ, agbẹjọro olujẹjọ, Barisita John Idoko, si fabọ jẹ igbimọ pe o wa nibẹ.