Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọrọ lilo ibori fun awọn akẹkọọ-binrin lawọn ileewe tawọn ajọ ẹlẹsin Kristẹni da silẹ, ṣugbọn to wa labẹ isakoso ijọba Kwara to ti n da wahala silẹ lati bii ọsẹ meloo kan sẹyin nireti wa pe yoo niyanju bayii, nitori bijọba ti ṣe fọwọ si lilo ibori ọhun lawọn ileewe tọrọ kan.
Ijọba ti waa paṣẹ fun ẹka to n mojuto eto ẹkọ lati ṣi awọn ileewe mẹwaa ti wọn ti pa lọsẹ to kọja latari ede-aiyede to bẹ silẹ lori hijaabu.
Atẹjade kan latọwọ akọwe ijọba, Ọjọgbọn Mamma Sabah Jibril, lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, ni gbogbo akẹkọọ-birin to jẹ Musulumi, to wa nileewe tijọba n ṣakoso lo lẹtọọ lati lo hijaabu.
Bakan naa nijọba ni ẹka to n mojuto eto ẹkọ yoo gbe ibori kan jade ti gbogbo ileewe patapata yoo maa lo.
Ijọba ni akẹkọọ-binrin to ba wu lati lo hijaabu, yala lawọn ileewe ijọba ati awọn to jẹ ti ẹlẹsin Kristẹni, ṣugbọn tijọba n dari, lẹtọọ lati lo o.
Ijọba tun ni gbogbo akẹkọọ lanfaani lati ṣe ẹsin rẹ lai si pe ẹnikan n da wọn lọwọ kọ.
Atẹjade naa ni gbogbo ileewe mẹwẹẹwa tijọba ti pa lọsẹ to kọja maa di ṣiṣi lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹta, ọdun yii.
Ijọba ni oun gbe igbesẹ naa lẹyin ipade to waye laarin Gomina Abdulrahman Abdulrazaq atawọn adari ẹsin mejeeji ati ni ibami pẹlu aṣẹ ile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun to ti ṣaaju fontẹ lu lilo hijaabu fawọn akẹkọọ-binrin Musulumi lawọn ileewe.
O waa gba awọn adari ẹsin mejeeji nimọran lati maa gbe pọ ninu irẹpọ, ki wọn si ṣọra fun sisọ ọrọ to tun le da omi alaafia ilu ru.