Adewale Adeoye
Awọn ọlọpaa Nebraska, lorileede Amẹrika, ti mu Abilekọ Erin Ward, ẹni ọdun marundinlaaadọta, to jẹ olukọ nileewe girama kan lagbegbe naa, ẹsun ti wọn fi kan an ni pe inu mọto lo ti tẹdii silẹ fun ọkan lara awọn akẹkọọ ileewe rẹ, tiyẹn si ba a sun karakara ninu mọto Honda Pilot kan, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.
ALAROYE gbọ pe olukọ agba nileewe girama kan ni Erin, ṣugbọn o n yan akẹkọọ rẹ to jẹ ọmọ ọdun mẹtadinlogun lọrẹẹ ikọkọ. Nigba ti olukọ naa ko le mu un mọra mọ lo ba ranṣẹ pe akẹkọọ ọhun pe ko waa b’oun lagbegbe Nebraska, b’ọmọkunrin naa ṣe wọnu mọto rẹ lẹyin ni wọn ti bẹrẹ si i kona bo ara wọn.
Awọn ti wọn ṣakiyesi pe mọto naa n mi ju bo ṣe yẹ lọ, ti Erin si n yata ni wọn ranṣẹ pe awọn ọlọpaa pe ki wọn waa wo ohun to n ṣẹlẹ lagbegbe awọn.
Gbara tawọn ọlọpaa de tawọn ololufẹ meji naa ri i pe ilẹ ti mọ ba awọn ni akẹkọọ ọhun sare jokoo saaye dẹrẹba, o si fi ibẹru wa ọkọ naa kuro nibẹ, ṣugbọn nitori pe ko mọ mọtoo wa daadaa, niṣe lo sọ ori mọto na m’ọbi kan, tawọn ọlọpaa si gba a mu loju-ẹsẹ.
Ọkan ninu awọn ọlọpaa agbegbe naa, Douglas County, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn kan ti wọn ṣakiyesi pe mọto naa paaki fun aimọye wakati ni wọn pe awọn lori foonu, tawọn si lọ sibe, awọn ṣakiyesi pe awọn ololufẹ meji ni wọn n bara wọn sun ninu mọto ọhun. Bi wọn si ti ri awọn ni akẹkọọ ọmọ ọdun mẹtadinlogun ti olukọ naa n ba ṣere ifẹ ti wa mọto ọhun kuro nibẹ pẹlu ibẹru bojo. O pada fi mọto ọhun nijamba lasiko to n wa a lọ, a gba a mu, a ri kaadi idanimọ ileewe, ‘Omaha Public Schools’ lapo rẹ, ileewe naa ni olukọ naa paapaa ti n kọ awọn akẹkọọ lẹkọọ iwe’.
Olukọ naa ti jẹwọ pe loootọ lawọn mejeeji n bara awọn sun ninu mọto ọhun. Alukoro ni awọn maa too foju olukọ ileewe naa bale-ẹjọ