Ki aye ma sọ mi lẹnu, ko ma si di pe awọn mi-in n ro erokero nipa ọrọ ọmọ mi, Sẹki, ki wọn ma ni boya inu mi ko dun ni, mo ni ki Safu jẹ ka ki wọn daadaa nigba ti a de. Ohun ti a si ṣe naa niyẹn, emi pẹlu ẹ, a ki gbogbo awọn ti wọn wa loju agbo, nigba ti mo si ti ki wọn tan, mo lọọ ba Iya mi, mo ki wọn ku oriire, mo ba Iya Dele naa sọrọ, mo si ki Aunti Sikira pe o ku aṣeyẹ. Lẹyin naa ni mo fa Safu wọle, mo ni ko lọ sile karun-un ile wa, obinrin kan to n ta ọti oriṣiiriṣii nibẹ, Ibo ni, Iya Ema, mo ni ko lọọ ko ọti bia wa, ko si ra Ṣinaapu ati waini igo kọọkan si i.
Mo kuku mọ ohun ti awọn araabi n mu. Nitori ẹ, mo ni ko ra katiini Sitaotu nla kan, katiini Sitaotu kekere kan, ko ra katiini Guda, ko ra ti Gobaagi kan ti wọn ni wọn ṣẹṣẹ n ṣe, ko si ra Turọfi kan si i fun wọn, ibi ti wọn ba le mu un de ni. Nigba ti wọn ko gbogbo ọti naa fun wọn, niṣe ni wọn pariwo gee, ti wọn n pe “Mama niyẹn! Olowo ṣeun gbogbo tan!”. Awọn ti wọn si jẹ ọrẹ Alaaji ti wọn ju mi lọ n pariwo “Ọmọ mi niyẹn! Walahi, ọmọ ju ọmọ lọ!” Mo mọ pe ọti lo n pa gbogbo wọn, emi o si raaye tiwọn yii, mo yaa ni ki Safu jẹ ka lọọ sun.
Mo ti mọ pe bi nnkan ṣe n lọ yii, Aunti Sikira ni yoo ko Alaaji girigiri bi wọn ba mu ọti wọn yo tan, bi Safu ba si wa nibẹ, yoo da ija silẹ ni. Nitori ẹ ni mo ṣe mu oun lọ sọdọ mi, mo si jẹ ko jẹun daadaa, mo ni ki oun naa lọọ mu waini kan to jẹ olomi ọṣan ninu firiiji, o tun jẹ ṣikin dindin to wa nibẹ, oun naa ni oun ti gbadun ikomọ. Bi a ṣe ṣe e niyẹn. Ohun ti n oo wa mọ ni pe ija ni n oo fi gbogbo ọjọ marun-un ti yoo tẹle ọjọ naa pari, bo tilẹ jẹ pe ọkan wa nibẹ to jẹ ija ifẹ, iyẹn ija Akin ati awọn ẹbi ọmọ to fun loyun. Kekere ma kọ!
Ija to kọkọ ṣẹlẹ ni ti Aunti Sikira ati obinrin ti awa lọọ ra ọti lọwọ ẹ yẹn, Iya Ema. Aṣe ọpọlọpọ ọti ti wọn mu yẹn, awin ni wọn lọọ gba a, ti Aunti Sikira si ti leri pe lọjọ keji loun yoo ko gbogbo owo ọti ti awọn gba wa. Boya o fẹẹ gba owo naa lọwọ ọkọ ẹ ni o, boya oun ati ọkọ ẹ lo jọ sọ ọ ni o, boya oun si ṣe ti ara ẹ ni o, Iya Ema ṣaa wa, o ni oun fẹẹ gba ẹgbẹrun mọkandinlọgọta, pe iye ọti ti wọn waa gba lọwọ oun niyẹn. O ni wọn mu Hẹnẹsi mẹrin, wọn mu ọkan bayii ti wọn ni wọn n ta ni ẹgbẹrun mẹjọ ki wọn too waa ko ọpọlọpọ bia le e.
Oke ni mo wa ti mo ti n gbọ ariwo. Iyẹn jẹ ọjọ kẹrin ti wọn ti dana faaji. Iya Ema loun ko ri Aunti Sikira titi ti ilẹ fi ṣu lọjọ keji to ni oun yoo fun oun lowo, nigba ti ilẹ si n ṣu lọ, oun ranṣẹ si i pe ko ri oun gẹgẹ bii adehun, lo ba ni oun ko raaye de banki ni. Ẹ gbọ irọ buruku! Aunti Sikira n lo banki! Haa, mo gbọmi-in! Ẹni to fi ẹnu ara ẹ sọ femi pe wọn ti ti akaunti oun pa nigba ti oun jẹ wọn ni gbese kan ti oun ko san an, pe oun gba owo alajẹṣẹku nibẹ, nigba toun ko si ri i san ni wọn ba bulọọku oun.
Ẹni ti ko ni banki to n lọọ n purọ fun iya ọlọti pe oun ko raaye de banki yẹn. Nigba to ṣaa di ọjọ kẹrin pati, ija buruku ṣẹlẹ, laaarọ kutukutu, mo ṣaa n gbọ ariwo pe, “Owo naa da! O ya jẹ ka lọ sidii ATM! Irọ lo n pa, ko sowo lọwọ ẹ! Onigbese lo fẹẹ ya, wọn dẹ ti kilọ fun mi tẹlẹ!”
Emi ati Safu wa loke, a n woran wọn. Ṣugbọn nigba to bẹrẹ si i sọ pe Alaaji nkọ, oun fẹẹ sọrọ ẹ fun Alaaji, ti mo si mọ pe ọkọ mi wa nile ko jade ni. Mo ni ki Safu lọọ beere iye owo ọti obinrin naa, ko lọọ ko o fun un ko yee pariwo le wa lori. Ni Safu ba lọ! Lobinrin yẹn ba sọye ẹ fun un.
Ṣugbọn inu n bi mi ṣuu, o n bi mi gan-an. Nigba ti Safu sanwo tan ni mo ba sare lọ sisalẹ, Safu gan-an ko ri mi bẹẹ yẹn ri. Mo mọ pe ti mo ba lọ sọdọ Aunti Sikira, iranu ni n oo maa gbọ. Agbaaya kan kuku tiẹ loun, nigba to ti gbọ iro mi pe mo n bọ loke lo ti sa wọle, mo gbọ to rọra tilẹkun to yi kọkọrọ si i, oniranu! Mo mọ pe ko ni i ṣi i bi mo kanlẹkun yẹn. Emi o kuku tiẹ ba tiẹ lọ, ọdọ ọkọ ẹ lemi n lọ. Nigba ti mo debẹ, ojiji ni mo wọle, mo ba Alaaji to ka guọ sẹgbẹẹ kan, mo mọ pe gbogbo ohun to ṣẹlẹ lo gbọ, o wa nibẹ to n woran.
Ohun ti ko mọ ni pe mo maa ja waa ba oun bẹẹ, ibi to ṣi ka guọ si yẹn ni mo ba a. Ni mo ba lọgun le e, “Owo mi da, owo mi da kiakia! Adojutini agbalagba ..! ” Bi mo ti ni ki n maa ka eebu gbogbo to wa lẹnu mi le e lori, bẹẹ ni Safu pe mi, emi o kuku tiẹ mọ pe o n tẹle mi. “Iyaaami! Ṣẹ ẹ waa maa pariwo le Dadi lori nitori aadota ẹgbẹrun ni! Ṣebi ẹyin le ni ki n ma maa pariwo nile! Pe awọn araale o gbọdọ gbohun wa!” N lo ba sare kunlẹ, lo n fọwọ pa mi lẹsẹ. N ko si le sọrọ kan titi to fi fa mi lọwọ pada soke, ni mo ba n laagun yọbọ, inu ti bi mi.
Safu naa ko sọro, o lọọ fun mi lomi tutu, oju wa bẹrẹ si i ti mi. Iyẹn ni pe emi naa le binu to bayii! O ya mi lẹnu. Ohun to si bi mi ninu ju ni pe itiju ni awọn eeyan naa fẹẹ da si mi lara. Ṣe o ṣee gbọ seti pe ọkọ Iya Biọla ra ọti ko sanwo, tabi ki wọn maa pariwo onigbese le wọn lori ninu ile ti mo n gbe, ile ọkọ mi! Ṣe ki i ṣe isọkusọ ni awọn eeyan yoo maa sọ nipa mi! Wọn ko si sọ fun mi nigba ti wọn n jẹ gbese! Ọtọ lẹni to ṣekomọ, ọtọ lẹyin ti ẹ jẹ gbese! Awọn mejeeji, tọkọ-tiyawo, wọn ko si wa sibi ti a ti sọmọ lorukọ! Ewo waa ni inawo apa!
Bi ẹ ba si fẹẹ na ina apa, ṣebi yoo jẹ owo tiyin, ki labọrọ jẹ gbese nitori aṣehan. O dun mi o. Ṣugbọn Safu o jẹ, ko jẹ ki n ṣe nnkan kan.Nigba ti mo si ti jokoo, ti mo ti tun ro o diẹ lọrọ naa ti bẹrẹ si dun mi, ti mo tun n da ara mi lebi pe mo sọrọ si ọkọ mi. Oun lo si fa a, oun naa mọ pe n ko ṣe iru ẹ ri. Aṣe Safu n wo mi, o n ṣọ oju mi, nigba to si ri i pe mo n da ara mi lẹbi yẹn, o tun sun mọ mi, o fọwọ pa mi lara, o ni, “Ko sẹni ti ko ni i dun, Dadi naa yoo mọ pe ohun ti awọn ṣe bi yin ninu ni, ẹ ki i kuku ṣe bẹẹ. Ẹ ma ro o, ko sẹni ti ki i binu o!”
Nigba ti a yanju iyẹn tan ni ti Sẹki ati ọkọ ẹ yi wọle, a ko si ti i yanju iyẹn ti ọrọ Akin fi de o! N oo ṣalaye awọn iyẹn fun yin lọsẹ to n bọ.