Lọla Ojo
‘‘Awọn aṣẹwo ni mo na miliọnu kan Naira fun ninu owo (1.3m) to kan nibi iṣẹ ijinigbe ti a ṣe’’. Ọmọkunrin kan, Isiaka Hamidu, ọkan ninu awọn ikọ ajinigbe mẹrin tọwo awọn ọlọpaa to n mojuto iwa ọdaran to ba lagbara ju, iyẹn Inteligence Response Team lọ sọrọ yii nigba tọwọ tẹ wọn, to si n sọ bi oun ṣe na owo to ri.
Ọmọkunrin ẹni ọgbọn ọdun naa lo ko awọn ikọ kan ninu iwa ọdaran jọ, to si fun wọn ni gbogbo aṣiri ti wọn nilo lati ji iyawo gbajumọ oniṣowo kan nipinlẹ Rivers, Abilekọ Hassana Adamu.
Ikọ awọn ọlọpaa to wa fun iṣẹ iwa ọdaran to ba lagbara yii, eyi ti DCP Tunji-Disu dari ni wọn mu awọn afurasi ajinigbe naa, iyẹn Isiaka Hamidu, ẹni ọgbọ ọdun, eyi to wa lati ipinlẹ Adamawa, Nwasaneo Goodluck, ẹni ọdun mẹrinlelọgbọn, Victor Nwidee, ẹni ọdun mọkandiinlọgbọn, ThankGod Bariledun, ẹni ọdun mẹrindinlogoji, ti gbogbo wọn wa lati ipinlẹ Rivers.
Hamidu to mu iṣẹ ijinigbe yii lọọ ba wọn ṣalaye pe ọkan ninu awọn ẹgbọn oun lo ba Alaaji Musa Ahmad ti wọn ji iyawo re gbe yii ṣiṣẹ fun odidi ọdun mọkanla. Nigba to si kuro lọdọ rẹ to lọọ ṣegbeyawo, ẹgbẹrun lọna lọna ọtalerugba o din mẹwaa (250, 000) ni ọkunrin naa fun un. O ni, ‘Inu mi ko dun si eleyii, nitori gbogbo eeyan lo mọ pe okunrin naa lowo lọwọ, o si le fun ẹgbọn mi ju iye to fun un lọ to ba fẹẹ ṣe bẹẹ. Eyi lo jẹ ki n pinnu lati ji oun tabi eyikeyii ninu mọlẹbi rẹ gbe.
‘Lẹyin ti mo ṣe ipinnu yii lọkan mi ni mo lọọ ba Goodluck, to jẹ ọrẹ mi ta a ti jọ wa tipẹtipẹ. Inu bi oun paapaa nigba ti mo sọ fun un, oun lo si mu amọran ijinigbe yii wa.
‘Goodluck lo pe ẹni to dari iṣẹ ijinigbe ti wọn ṣe naa, iyẹn Ojukwu. Oun lo ṣe gbogbo eto ti wọn fi ri obinrin naa ji gbe lẹyin ti mo ti fi ile rẹ han wọn, bo tilẹ jẹ pe emi ko tẹle wọn lọ ki wọn ma baa da mi mọ.
‘Miliọnu lọna ogun (20m) ni wọn gba nibi ijinigbe naa, miliọnu kan ati ọọdunrun Naira lo kan emi nibẹ’’.
Nigba ti wọn beere ohun to fi owo naa ṣe, Hamidu ni, ‘Miliọnu kan ninu rẹ ni mo lo lati maa ba awọn aṣẹwo sun. Niṣe ni mo gba otẹẹli, mo si n pe aṣẹwo si inu otẹẹli mi yii ta a jọ n sun lalaalẹ fun odidi oṣu kan. O kere tan, mo maa n ba aṣẹwo meji sun lalẹ ọjọ kan, ẹgbẹrun lọna ogun Naira ni mo si n san fun ẹnikọọkan wọn. Oko agbado ni mo lọọ fi ọọdunrun Naira to ku da si abule wa’. Bẹẹ ni ọmọkunrin naa sọ.