Florence Babaṣọla
Lati ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹsan-an, ọdun to kọja, ti awọn ikọ alaabo kan ti wọn wa ọkọ JTF ti le awọn ọdọ mẹrin kan lalepajude, eleyii to yọri si iku ọkan lara wọn, lawọn araalu ti n lọgun pe ki awọn agbofinro gbe orukọ awọn ti wọn wa ninu mọto naa jade.
Nigba ti igbimọ oluwadii oniruuru ẹsun ta ko SARS tun bẹrẹ ijokoo l’Oṣogbo, awọn mọlẹbi ọmọ to doloogbe naa, Idris Ajibọla, lọ sibẹ pẹlu agbẹjọro wọn, Kanmi Ajibọla, wọn ni awọn fẹẹ mọ awọn to ṣekupa ọmọ naa, kijọba si fun awọn ni owo gba-ma-binu biliọnu marun-un naira.
L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni alaga igbimọ naa, Adajọ-fẹyinti Akin Ọladimeji, kede pe ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti pari iwadii wọn, wọn si ti mọ awọn ikọ alaabo maraarun-un ti wọn wa ninu mọto JTF 04 ti wọn fi ṣiṣẹ laabi ọhun.
Orukọ awọn maraarun-un, gẹgẹ bi wọn ṣe fi sita, ni Ejigbo Audu (NPF), Benjamin Ogunsẹsan (NPF), Jẹkayinfa Olutosin (NSCDC), Raji Adewale (SSS) ati Hammed Yusuf (NAF).
A oo ranti pe ṣe ni Idris Ajibọla atawọn ọrẹ rẹ gbe mọto Toyota Corrola Sallon to ni nọmba Abuja KUJ 553 LY wa sileetaja nla kan niluu Oṣogbo lati Ọfatẹdo ti wọn n gbe, bi wọn ṣe n lọ lawọn ikọ JTF yii n sare tẹle wọn.
Ibẹrubojo ti ẹni to wakọ yẹn fi n sare lo jẹ ko fori sọ opo-ina, to si takiti sinu gọto nla kan, loju-ẹsẹ si ni Idris Ajibọla ku, ti awọn yooku si fara pa pupọ.
Nibi ijokoo igbimọ naa lagbẹjọro mọlẹbi Ajibọla ati Iya Idris ti gboṣuba fun ijọba Ọṣun pẹlu bi wọn ṣe fun ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran lanfaani lati gbe orukọ naa sita, ti wọn si fi mu un wa siwaju igbimọ.
Ninu abajade iwadii naa nijọba ti fọwọ si i pe ki awọn ti ajere iwa naa ṣi mọ lori fara han ni ẹka to n ba awọn to ba ṣiwa-hu lẹnu iṣẹ wi ni agọ ẹnikọọkan wọn lati le sọ ohun ti wọn ri lọbẹ ti wọn fi waro ọwọ.
Nibi ijokoo igbimọ naa ni alaga wọn ti gba akọsilẹ agbẹjọro olupẹjọ, to si ṣeleri pe awọn yoo dabaa ohun to ba tọ funjọba lati ṣe lori ẹ.