Adewale Adeoye
Ọkan pataki lara awọn Alukoro eto iroyin fun Alaaji Atiku Abubakar, Ọgbẹni Prank Shaibu, ti sọ pe gbogbo ete pẹlu irọ buruku kan ti ondije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu, n pa laimọye ọdun sẹyin nipa ẹsun ti wọn fi kan an pe o gbe egboogi oloro niluu oyinbo, to si yọnda owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lona ẹẹdẹgbẹta ($460) dọla owo ile okeere fawọn alaṣẹ orileede naa ni oootọ rẹ ti n foju han kedere bayii. Eyi ko sẹyin bi wọn ṣe sọ niwaju ile-ẹjọ to n gbọ awọn ẹsun to su yọ lasiko idibo (Tribunal) to n gbẹjọ rẹ lọwọ niluu Abuja, pe owo ohun jẹ ti eyi to ni i ṣe pẹlu owo-ori ti Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu ko san niluu oyinbo, pe owo ọhun ko ni nnkan kan an ṣe pẹlu ẹsun gbigbe egboogi oloro rara.
Ọgbẹni Prank Shaibu lo sọrọ ọhun di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun yii, lakooko to n ba awọn oniroyin kan sorọ niluu Abuja. O ṣalaye pe ootọ awọn irọ buruku ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu pẹlu oluranlọwọ rẹ n pa kiri lori ẹsun ọdaran ti wọn fi kan an ti foju han kedere nile-ẹjọ Tiraibuna ti ẹgbẹ APC pẹlu Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti lọọ pẹjọ niluu Abuja bayii.
Ọgbẹni Shaibu ni, ‘Funra Festus Keyamo lo lọ sori tẹlifiṣan nilẹ yii, to sọ pe owo to din diẹ ni ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (460$) dọla owo ilẹ okeere ti awọn alaṣẹ ijọba ilẹ okeere gbẹsẹ le to jẹ owo Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ki i ṣe owo to ri nidii okoowo egboogi oloro rara, ṣugbọn owo naa jẹ ti owo-ori ti ko fẹẹ san. Ni kukuru, wọn ti gba pe loootọ ni wọn fẹsun pe Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu gbe egboogi oloro kan an, bo tilẹ jẹ pe Tinubu paapaa ko ti i fi gbogbo ara gba pe loootọ ni.
O yẹ ko ye Tinubu pe ko si bo ṣe le ṣe e, ko si bo ṣe fẹẹ fa ọwọ aago sẹyin nipa ọrọ naa rara, ohun to daju ṣaka ni pe wọn ṣewadii rẹ daadaa nipa pe o gbe egboogi oloro niluu oyinbo,
‘’Aimọye miliọnu dola owo ilẹ okeere ni wọn ba ninu akanti rẹ lakooko naa, bẹẹ lo jẹ pe ẹgbẹrun meji aabọ dọla owo ilẹ okeere lo n gba loṣu nigba naa lọhun-un, o mọ-ọn-mọ yọnda lara owo ọhun fawọn alaṣẹ ijọba naa ni, ko ma baa ṣẹwọn.
‘‘Akoko ibo ti pari, ẹ sọ fun Aṣiwaju pe ko soootọ faraye gbọ, ko yee parọ, ẹ sọ fun un ko yee fọbọ lọ awọn ọmọ orile-ede yii mọ, ko sọ ibi gan-an to ti ri owo nla to wa lọwọ rẹ bayii.
Ọgbẹni Shaibu ni bi Aṣiwaju ba di aarẹ orile-ede yii, yoo ṣoro gidi gan-an fun ajọ to n gboogun ti gbigbe egboogi oloro nilẹ wa lati maa fowọ ofin mu awọn ọdaran, nigba to jẹ pe baba wọn lo wa nipo
Ni ipari ọrọ rẹ, o rọ awọn alaṣẹ ijọba ilẹ okeere pe ki wọn ṣeranlowọ gidi fun ẹka eto idajọ ilẹ wa, pẹlu fifun wọn ni gbogbo awọn ẹri ti wọn ti fẹsun ọdaran kan Aṣiwaju Bola Ahmed Tinubu lakooko to yọnda owo ọhun silẹ fun wọn.