Aṣiri ohun to fa a tawọn agbebọn fi pa ọga ọlọpaa n’Igangan niyi

Ọlawale Ajao, Ibadan

Awọn agbebọn tun pitu ọwọ wọn niluu Igangan pẹlu bi wọn ṣe ṣigun lọọ ka awọn agbofinro mọ agọ wọn, iyẹn teṣan ọlọpaa to wa nigboro ilu naa, ti wọn si yinbọn pa ọga ọlọpaa pẹlu ọkan ninu awọn afurasi ọdaran to wa lahaamọ ninu teṣan naa.

Lalẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to lọ yii lawọn ẹruuku ọhun ya wọ teṣan ọlọpaa naa tibọntibọn, ti wọn ba teṣan awọn agbofinro ọhun jẹ lẹyin ti wọn yinbọn paayan meji, ti wọn si ṣe olori awọn ọlọpaa nibẹ leṣe tan.

Igbakeji ọga ọlọpaa (DCO), teṣan naa pẹlu ọkan ninu awọn afurasi ọdaran to wa lahaamọ nibẹ ni wọn yinbọn pa nifọnnafọnṣu.

Bakan naa ni wọn ṣa DPO, iyẹn ọga ọlọpaa teṣan Igangan yii ladaa yannayanna to bẹẹ to jẹ pe diẹ lo ku ki ẹmi ọkunrin naa bọ mọ wọn lọwọ.

Awọn Tapa la gbọ pe wọn huwa ọdaju ọhun lati gbẹsan iṣẹlẹ kan to pa awọn pẹlu awọn ọlọpaa pọ n’Igangan.

Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, awọn ọlọpaa to n kaakiri ilu ọhun fun amojuto ni wọn da ọkọ kan duro, ṣugbọn kaka ki wọn duro, niṣe lawakọ naa tẹ ina mọ ọkọ, to n sare buruku lọ.

Ara fu awọn ọlọpaa pe o ṣee ṣe ko jẹ pe oniṣẹ ibi kan lawọn eeyan naa ni lati jẹ, n lọkan ninu wọn ba gbiyanju lati yinbọn mọ taya ọkọ awọn afurasi oniṣẹ ibi duro ni tipatipa.

Dipo ki ibọn ba taya ọkọ, awakọ lo ba. Ṣugbọn nigba ti awọn ọlọpaa yoo fi dé ọdọ awọn ẹhanna eeyan yii, wọn ti yara wọ awakọ ti ibọn ba ṣẹgbẹẹ kan ninu mọto, ẹlomi-in si bọ sidii ọkọ, n ni wọn ba tun ko ina bo mọto titi ti wọn fi sa lọ mọ awọn ọlọpaa lọwọ.

Ikanra iṣẹlẹ yii lo mu ki awọn Tapa yii ṣigun lọọ ka awọn agbofinro mọ agọ wọn niluu Igangan nibẹ, ti wọn si yinbọn pa igbakeji ọga ọlọpaa teṣan naa, ti wọn tun ṣa DPO, ibẹ ladaa yannayanna.

Nigba to n fidi iroyin yii mulẹ, Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, sọ pe ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ naa, CP Adebọwale Williams, ti lọọ ṣabẹwo si agọ ọlọpaa Iganna, bẹẹ niwadii ti bẹrẹ lati ti awọn odaju eeyan to yinbọn pa awọn eeyan bii ẹni pẹran naa mu.

Leave a Reply