Aṣiri tu! Adajọ ju Seriki-n-Fulani Kwara sẹwọn gbere, wọn lọgaa awọn ajinigbe ni

Ile-ẹjọ giga to fikalẹ siluu Ilọrin, ti ni ki Seriki-n-Fulani ipinlẹ Kwara, Alaaji Usman Adamu, aburo rẹ, ati ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Gidado Idris, lọọ lo iyooku aye wọn ninu ọgba ẹwọn, lẹyin ti wọn jẹbi ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan wọn.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọgbọnjọ, oṣu Kọkanla, ni ajọ ẹṣọ alaabo ọtẹlẹmuyẹ nilẹ wa, DSS, eyi ti Agbefọba, Ayoọla Akande, n ṣe iwadii lori ẹsun naa foju awọn ọdaran mẹtẹẹta han nile-ẹjọ.

Seriki-n-Fulani ati awọn meji yooku ni wọn lọọ ji ọkunrin kan, Abubakar Ahmed, gbe lagbegbe Sawmill, niluu Ilọrin, lọdun to kọja, ti wọn si gba  miliọnu kan Naira ki wọn too tu u silẹ lẹyin to lo ogunjọ lakata wọn.

Awọn ọdaran naa gba pe loootọ lawọn jẹbi ẹsun ijinigbe ti wọn fi kan wọn. Seriki-n-Fulani ni awọn ji Abubakar gbe kawọn le gbowo lọwọ rẹ ni.

Agbẹjọro fun awọn olujẹjọ bẹbẹ pe ki adajọ da awọn ẹsun ti wọn ka si awọn onibaara oun lọrun nu, nitori pe ko si awọn ẹlẹrii nibẹ nigba ti iṣẹlẹ naa waye.

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Adenikẹ Akinpẹlu, ni olupẹjọ ti fidi ẹri rẹ mulẹ kọja iyemeji nipasẹ awọn ẹlẹrii to ko wa sile-ẹjọ, ati pe awọn olujẹjọ naa ti fẹnu ara wọn sọ pe awọn jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

O ni ohun to ba oun lọkan jẹ ni pe olori agbegbe to yẹ ko maa daabo bo agbegbe rẹ lo tun lọwọ ninu ijinigbe nitori ifẹ owo.

Adajọ ni oun ran awọn ọkunrin naa lẹwọn gbere, ko le jẹ ẹkọ nla fun ẹnikẹni to le tun fẹẹ dan iru nnkan bẹẹ laṣa.

Leave a Reply