Faith Adebọla
Ojumọ kan, ara kan, lọrọ to n jade nibudo igbẹjọ lori awuyewuye to su yọ lori eto idibo aarẹ to kọja lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii. Tuntun to tun jẹ jade lasiko igbẹjọ to waye l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa yii, ni bi olupẹjọ, Alaaji Atiku Abubakar, ti i ṣe oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ati ẹgbẹ oṣelu rẹ ṣe ṣalaye nile-ẹjọ pe ẹrọ tuntun ti ofin sọ pe ajọ eleto idibo, Independent National Electoral Commission (INEC), yoo fi ṣakojọ ibo, ti wọn yoo si fi ṣe atare-tare rẹ sori ẹrọ ayelujara ti wọn n da esi ibo jọ si, iyẹn Bimodal Voter Accreditation System (BIVAS) kọ ni ajọ naa lo, ẹrọ mi-in ni wọn fẹyin pọn wọle ti wọn fi ṣe akojọ ibo naa, ti wọn si fi ṣe atare rẹ sori atẹ ayelujara wọn.
Wọn ni ko sidii meji ti INEC fi dọgbọn buruku yii ju ki wọn le raaye lo awọn ẹrọ ajeji ọhun lati ṣojooro ibo, lati yi ibo, ki wọn si le gb’ẹbi f’alare ninu esi idibo ọhun lọ.
Atiku ati PDP ni eyi lo fa a to fi jẹ pe lẹyin apamọ pabo ati adọgbọnsi wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti i ṣe oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) ni wọn kede pe o jawe olubori, bẹẹ irọ patapata ni.
Lati kin awijare wọn lẹyin, awọn olupẹjọ yii pe ẹlẹrii meji jade, Ọgbẹni Friday Egwuma to jẹ alamoojuto ibo nipinlẹ Abia ati Grace Timothy, to ṣamojuto ibo naa nipinlẹ Plateau, tawọn mejeeji wa lara awọn oṣiṣẹ fungba diẹ ti INEC yanṣẹ fun lasiko idibo ọhun. Awọn mejeeji si ni wọn fidi rẹ mulẹ pe gẹrẹ tawọn ti lo awọn ẹrọ BIVAS ti wọn fun awọn lati ṣaropọ ibo tawọn aṣofin agba atawọn aṣoju-ṣofin tan, tawọn si ti taari esi ibo naa sori atẹ ayelujara INEC lawọn ẹrọ BIVAS naa ti dẹnu kọlẹ, tawọn ko si ri i lo fun esi idibo ti aarẹ, niṣe lawọn wa ọgbọn mi-in da.
Bakan naa ni Atiku ati PDP ṣalaye pe ẹni ti INEC lo lati ṣe kokaari ẹrọ igbalode ati itakun ayelujara wọn, iyẹn Ọgbẹni Suleiman Farouk, lo dọgbọnkọgbọn kan lati ri i pe awọn ẹrọ BIVAS kan ko ni i ṣiṣẹ laarin asiko ti wọn ba fẹẹ fesi ibo ti aarẹ ṣọwọ. Wọn ni ọgbọn imọ ẹrọ ni wọn lo lati ja itakun to so ẹrọ BIVAS ati atẹ INEC Result Viewing, iyẹn IreV pọ, eyi tawọn eleebo n pe ni Data Management System (DMS).
Amọ awọn agbẹjoro olujẹjọ ta ko awọn alaye ati awijare olupẹjọ yii. Amofin agba, Abubakar Mahmud to n ṣoju fun INEC sọ pe apa kan eto ti INEC ṣe nigba ti ẹrọ BIVAS ba kọṣẹ lojiji ni lati lo ọgbọn mi-in, iru eyi ti ọkan lara awọn ẹlẹrii Atiku da yii.
Ni ti Alagba Wọle Ọlanipẹkun, amofin agba to ṣoju fun Aarẹ Bọla Tinubu ati Ọmọọba Lateef Fagbemi, amofin agba to ṣoju fun ẹgbẹ oṣelu APC, awọn mejeeji ni wọn ta ko Atiku, PDP atawọn agbẹjoro wọn, wọn ni ẹri atawọn ẹlẹrii ti wọn n ko wa siwaju ile-ẹjọ naa ta ko ofin igbẹjọ, tori awọn ẹri naa ko si lakọọlẹ nibẹrẹ pẹpẹ igbẹjọ yii. Tori ẹ, wọn ni kile-ẹjọ ma ṣe gba awọn ẹri naa wọle, ki wọn da a nu ni.
Igbimọ naa ti sun igbẹjọ siwaju di ọjọ mi-in lati pinnu boya wọn maa gba awọn ẹri wọnyi wọle abi wọn maa da a nu bii omi iṣanwọ ni.