Aderounmu Kazeem
Nibi ti ẹmi awọn eeyan kan ti ṣofozeem nibi iwọde to n lọ kaakiri Naijiria, owo biliọnu rẹpẹtẹ ni wọn sọ pe awọn eeyan kan ti fi gba sapo ara wọn bayii lọwọ ijọba.
Latigba ti iwọde ti bẹrẹ kaakiri orilẹ-ede yii, ti awon eeyan da ibinu bolẹ wi pe awon ko fẹ ajọ SARS mọ, iroyin to gba igboro kan bayii ni pe, aimọye biliọnu owo naira lawọn olokoowo nla kan tawọn mi-in ti wọn n dari awọn ọdọ kan ti gba sapo bayii.
Ninu ọrọ ti Ọmọyẹle Ṣoworẹ, ọga agba to nileese iroyin Sahara Reporters sọ lo ti sọ pe awọn eeyan kan wa, owo nlanla ni wọn ti fi iwọde ọhun gba lọwọ ijọba pẹlu ileri wi pe awọn yoo ba awọn to n ṣe iwọde kiri sọrọ, ti kaluku yoo si jokoo sile ẹ jẹẹ.
Ṣoworẹ sọ pe, adehun ẹyọ kanṣoṣọ toun le ba ẹnikẹni fọwọ si ni ki wọn gba ohun gbogbo ti araalu n fẹ, ati pe ẹnikan bayii, ko le fi abẹtẹlẹ kankan lọ oun lati kọyin si ohun ti ọmọ Naijiria n fẹ.
Ni ti Aisha Yesufu, obinrin ọmọ Hausa toun naa jẹ jafẹtọọ sọ pe, loootọ lawọn eeyan kan ti di olowo, ṣugbọn alaye ti oun ṣe fun ọga agba apapọ banki Naijiria (CBN), Ọgbẹni Godwin Emefiele ni pe, ti ijọba ba ti ṣe ohun ti araalu n fẹ, ko ni i si iwọde kankan mọ nibikibi ni Naijiria.
Ṣa o, ọkunrin kan ti wọn n pe ni Sẹgun Awosanya to ṣagbatẹru awọn to n ṣe iwọde ‘A ko fẹ ẹṣọ SARS mọ’ ti sọ pe loootọ ni awọn eeyan kan ti ja eto ọhun gba mọ awọn ti awọn da a silẹ lọwọ.
Ọkan lara awọn aṣoju ọdọ ti wọn tun fẹsun kan ni Debọla Williams, wọn loun lo sọ pe, o to gẹ, ki kaluku gbale ẹ lọ, ṣugbọn niṣe lo ni ọrọ ko ri bẹẹ rara, oun ko wi nnkankan ni toun.
Tẹ o ba gbagbe, lati nnkan bi ọjọ meloo kan sẹyin lawọn ọdọ kaakiri orile-ede yii ti n ṣe iwọde, ohun ti wọn si n beere lọwọ ijọba ni pe, ko fagile ẹṣọ to n gbogun ti idigunjale, nitori wọn ko ṣiṣẹ tijọba ran wọn mo, awọn eeyan ilu ni wọn n pa kiri, ti wọn si tun n ja wọn lole pẹlu.
Ọpọ eeyan lo ku o, bẹẹ lawọn ọlọpaa paapaa padanu ẹmi wọn. Ninu wahala ọhun ni ̀ọga ọlọpaa ti sare fofin de awọn SARS, ti Buhari paapaa si kede wi pe, oun naa fọwọ si i.
Sugbọn niṣe lawon ọmọ Naijiria ṣi kun oju titi bamu, bi wọn ṣe n ru posi Buhari, bẹẹ ni wọn n ṣepe gidi. Lojoojumọ ni iwọde ọhun n fẹju si i, to si ti fẹẹ kari gbogbo ipinlẹ ni Najiria atawọn ilẹ okeere ti awọn ọmọ Naijiria wa.