Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Ọrọ oṣelu ipinlẹ Ondo lọwọ ta a wa yii ti di egbinrin ọtẹ, bi wọn ṣe n pa ọkan ni omiiran tun n ru jade, ojumọ kan, wahala kan ni, lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 yii, tawọn ọmọ igbimọ aṣejọba ipinlẹ ọhun ti pada de lati ilu Abuja, nibi ti Aarẹ Bọla Tinubu ti lọọ ba wọn pari ija.
Ohun to kọkọ da ariwo nla silẹ lẹyin ipade alaafia ti wọn lọọ ṣe ọhun lọrọ ẹni to yẹ ko fi orukọ awọn adele alaga ijoba ibilẹ ṣọwọ sileegbimọ aṣofin fun ayẹwo, ifọrọwanilẹnuwo ati fifi ontẹ lu u.
Awọn ọmọ ẹgbẹ kan to ṣee ṣe ki wọn jẹ alatilẹyin Igbakeji gomina, Lucky Ayedatiwa, ni wọn kọkọ fariwo ta, ti wọn si fẹsun kan alaga ẹgbẹ All Progressive Congress, nipinlẹ Ondo, Ade Adetimẹhin, pe o ti ko awọn orukọ kan jọ, eyi to fẹẹ fi ṣọwọ sileegbimọ aṣofin gẹgẹ bii awọn adele ijọba ibilẹ mọkanlelaaadọta to wa nipinlẹ naa. Eyi ni ijọba ibilẹ mejidinlogun to ti wa nilẹ tẹlẹ lati ọdun 1976, atawọn ijọba ibilẹ idagbasoke mẹtalelọgbọn tijọba Rotimi Akeredolu ṣẹṣẹ da silẹ.
Awọn eeyan naa ni kawọn alaṣẹ ẹgbẹ All Progressive Congress, l’Abuja, tete pe Adetimẹhin, ki wọn si ba a sọrọ nibi to ti n gbọ, nitori pe wahala mi-in lo tun fẹẹ maa fa lẹsẹ pẹlu awọn orukọ adele alaga ijọba ibilẹ to fẹẹ fi ranṣẹ, nigba ti igbakeji gomina ṣi wa nipo.
Opin ọsẹ to kọja yii lariwo mi-in tun jade sigboro, ninu eyi tawọn alatilẹyin Ayedatiwa kan ti fẹsun kan olori awọn aṣofin ipinlẹ Ondo, Ọladiji Ọlamide, pe o ti fẹẹ maa gbe igbesẹ ta ko ipade alaafia ti Aarẹ Tinubu ba wọn ṣe pẹlu iroyin ti awọn n hu gbọ pe o ti ranṣẹ pe awọn eeyan kan ti wọn fẹẹ fọrọ wa lẹnu wo gẹgẹ bii adele alaga awọn ijọba ibilẹ.
Wọn ni ko yẹ ki Ọladiji yọnda ara rẹ fawọn oloṣelu kan ki wọn ti i nitikuti, nitori ohun to le da omi alaafia ilu ru ni.
Ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, laṣiiri lẹta ti olori ile fi ranṣẹ sawọn ti wọn fẹẹ yan gẹgẹ bii adele alaga tuntun si awọn ijọba ibilẹ naa tu sita, ọrọ soki to wa ninu lẹta ọhun ni pe wọn gbọdọ fara han niwaju awọn aṣofin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn pẹlu awọn iwe-ẹri wọn.
Awada tabi ahesọ lasan lawọn eeyan kọkọ pe e, afigba to di aarọ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, loootọ, tawọn ọkọ bẹmbẹ bẹmbẹ gunlẹ sinu ọgba ileegbimọ aṣofin to wa ni Alagbaka, niluu Akurẹ.
Ko si pẹ rara tawọn aṣofin wọnyi fi bẹrẹ ijokoo, nibi ti wọn ti kede orukọ awọn adele alaga tuntun naa pẹlu igbekeji wọn.
Ninu ọrọ apilẹkọ ti olori ile ka sita lasiko ijokoo ọhun lo ti ni: ‘‘Ẹyin eeyan mi, ẹ gba mi laaye ki n ki yin kaabọ sileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ondo lẹyin rogbodiyan oṣelu to ti n mi ipinlẹ yii titi lati ọjọ pipẹ wa. Lai siyemeji lọkan mi, igbagbọ mi ni pe olukuluku wa la ja fitafita lati ṣiṣẹ lori idi ti wọn fi yan wa sipo ta a wa gẹgẹ bii aṣoju awọn araalu.
‘‘Ko sibi ta a ti kọja aaye wa ninu awọn igbesẹ ta a gbe, gbogbo ohun ta a ṣe lo wa ni ibamu pẹlu ofin Naijiria, bo tilẹ jẹ pe oriṣiiriṣii orukọ tawọn obi wa ko sọ wa ni wọn n pe wa nigba naa, ṣugbọn a dupẹ pe imọ wa pada ṣọkan lati mu ipinlẹ Ondo tẹsiwaju. Loootọ ati lododo, ko sohun to buru rara ninu awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin, ara ohun ti a n pe ni ijọba awa-ara-wa ni ibeere ati idahun wa.
‘‘Ohun ti awọn iṣẹlẹ wọnyi tun n tọka si ni ṣiṣe igbelewọn ati odiwọn iṣẹ iriju wa, a si dupẹ lọwọ Aarẹ Bọla Tinubu atawọn aṣaaju ẹgbẹ ti wọn ba wa da sọrọ naa lasiko, leyii to mu ki alaafia pada jọba, nitori ki i si idagbasoke nibi ti rudurudu ba ti wa, ayafi ta a ba fẹẹ tan ara wa jẹ lo ku.
‘‘Ki ọrọ yii le ye yin-in daadaa, ẹ jẹ ki n ka abajade ohun ta a fẹnu ko le lori ninu ipade ta a ṣe pẹlu Aarẹ Tinubu l’Abuja fun yin-in eyi ti i ṣe iwọnyi:
‘Ki gbogbo nnkan wa bi wọn ṣe wa tẹlẹ ninu ẹgbẹ, ki igbesẹ yiyọ igbakeji gomina dawọ duro lẹyẹ o ṣọka, gbogbo iwe ẹjọ ti wọn pe si kootu gbọdọ di fifaya, bẹẹ ni ko sẹni to gbọdọ tu igbimọ aṣejọba ka.
‘‘Igbakeji gomina gbọdọ kọwe pe mo fipo silẹ, eyi ti ko ni i ni ọjọ lori, ko si fi ṣọwọ si Aarẹ.
‘‘Ki awọn adari ati ipilẹ ẹgbẹ wa bi wọn ṣe wa tẹlẹ, ki Ọnarebu Lucky Ayedatiwa si maa tẹsiwaju ninu ojuṣe rẹ gẹgẹ bii igbakeji gomina.
‘‘Awọn mẹta yii, Ade Adetimẹhin, to jẹ alaga ẹgbẹ All Progressive Congress, nipinlẹ Ondo, Akọwe ijọba, Abilekọ Ọladunni Odu, ati Olori awọn aṣofin, Ọnarebu Ọladiji Ọlamide, ni a yan gẹgẹ bii alamoojuto fun gbogbo awọn ohun ta a ti sọ wọnyi. Leke gbogbo rẹ, mo rọ gbogbo awọn tinu n bi ki wọn fọwọ wọnu, nitori ta a ba gbagbe ọrọ ana, o ṣee ka ma ri ẹni ba ṣere, mo fẹ ki gbogbo wa jọ fọwọsowọpọ fun idagbasoke ipinlẹ Ondo.
‘‘Ẹ jẹ ki n si fi asiko yii kilọ fawọn oloṣelu tabi awọn eeyan ti wọn si fẹẹ maa dana ogun pe ikoko ko ni i gba omi ko tun gba ẹyin mọ ọn rara, awa aṣofin ti ṣetan ati lo gbogbo agbara wa lati fi da seria fun ẹnikẹni to ba fẹẹ gbe saraa rẹ kọja mọsalasi.
Ẹyin ẹgbẹ mi, ẹ oo ranti pe ijọba ipinlẹ Ondo la ipa rere pẹlu igbesẹ to gbe lati da awọn ijọba ibilẹ idagbasoke tuntun mẹtalelọgbọn silẹ.
‘‘Gbogbo ilana to yẹ la tẹle lati fidi igbesẹ itẹsiwaju yii mulẹ labẹ ofin ti Gomina Rotimi Akeredolu naa si ti buwọ lu abadofin rẹ.
Lonii, a n fi itan tuntun balẹ nipinlẹ Ondo pẹlu ba a ṣe n ṣe ayẹwo fawọn adele alaga fawọn ijọba ibilẹ tuntun naa ati eyi to ti wa nilẹ tẹlẹ fun idagbasoke awọn eeyan wa’’. Bayii ni olori awọn aṣofin pari ọrọ rẹ.
A ko ti i gbọ ohunkohun lati ọdọ awọn alatilẹyin Ayedatiwa lori yiyansipo awọn adele alaga tuntun yii lasiko ta a n ko iroyin yii jọ.
Ṣugbọn ALAROYE gbọ pe ṣe lawọn alatilẹyin Akeredolu mọ-ọn-mọ gbe igbesẹ yii nitori ahesọ ati ihalẹ awọn kan pe o ṣee ṣe ki wọn kede orukọ Ayedatiwa gẹgẹ bii Adele Gomina laipẹ.
Ko ti i sẹni to mọ ibi ti ọrọ naa yoo yoo yọri si.