Adewale Adeoye
Pẹlu bi awọn araalu gbogbo ṣe ti n fẹhonu han lori igbesẹ awọn alaṣẹ ijọba apapọ ilẹ wa lori bi wọn ṣe yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu. Ẹgbẹ awọn onimọto kan ti wọn n pe ni ‘Lagos State Parks And Garages’ (LSPG) ti sọ pe gbagbaagba bayii lawọn wa lẹyin bi olori orileed yii, Aarẹ Bọla Ahmed Tinubu ṣe yọ owo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa. Ti wọn si lawọn fara mọ igbesẹ ọhun daadaa.
Alhaji Sulaimon Ọjọra to jẹ igbakeji ẹgbẹ awọn dẹreba LSPG, to gba awọn ọmọ ẹgbẹ naa lalejọ l’Ọjọruu, Wesidee, ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹfa, ọdun yii, dupẹ gidi lọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lori bi wọn ṣe loye kikun nipa ohun to n ṣẹlẹ lorileede yii ati iha ti wọn kọ si ipinnu Aarẹ Tinubu lati yọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa lakooko ijọba rẹ.
Ṣa o, Ọjọra ni awọn alaṣẹ ijọba gbogbo ti n ṣiṣẹ labẹnu bayii lati bu ororo itura si inira ti yiyọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa le mu ba awọn araalu.
Bakan naa lo gba awọn ọmọ ẹgbẹ ọhun nimọran pe ki wọn ma ṣafikun owo mọto wọn ju bo ṣe yẹ lọ, paapaa ju lọ, nigba ti wọn mọ pe nnkan ko fara rọ laarin ilu lakooko yii. O ni ẹgbẹ naa ti yan igbimọ ẹlẹni meje kan ti yoo maa lọ kaakiri aarin ilu lati maa fọwọ ofin mu awọn dẹrẹba kọọkan ti wọn ko ba tẹle ofin ti ẹgbẹ naa gbe kalẹ lori pe ki won ma ṣe afikun owo mọto ju bo ṣe yẹ lọ nipinlẹ Eko.
Ojọra ni, ‘Ko sẹni ti ko mọ rara pe inira pẹlu ipọnju ni ọrọ yiyọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa yoo kọkọ mu ba awọn araalu ni gbara ti wọn yọ ọ yii, ohun kan to daju ṣaka ni pe awọn araalu yoo jẹ anfaanu igbesẹ Aarẹ Bọla Tinubu lopin ohun gbogbo. Mo wa n rọ awọn araalu pe ki wọn ṣe suuru fun iṣakoso ijọba tuntun yii, o daju pe yoo wa ojutuu si inira ti ọrọ yiyọwo iranwọ lori epo bẹntiroolu naa n mu ba araalu.’
Ni ipari ọrọ rẹ, Ọjọra tun gba awọn ẹgbẹ awakọ gbogbo lorileede yii nimọran lati wo awokọṣe rere ti ẹgbe LSPG hu yii, ki awọn paapaa ṣe bẹẹ laipẹ ọjọ.