Stephen Ajagbe, Ilorin
Ijọba ipinlẹ Kwara ti ni eto idibo ijọba ibilẹ ko le waye bayii nitori awọn idiwọ ati ipenija kan tijọba n dojukọ.
Agbefọba agba to tun jẹ kọmiṣanna feto idajọ, Salam Jawondo ṣalaye pe eto idibo naa yoo to ọdun to n bọ ko too le waye.
Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni saa awọn alaga ijọba ibilẹ mẹrindinlogun to wa ni Kwara pari. Bo tilẹ jẹ pe kete tijọba Gomina Abdulrazaq Abdulrahman gbakoso lo ti paṣẹ fun wọn lati lọọ rọọkun lati faaye gba iwadii ti ọn fẹẹ ṣe lori bi wọn ṣe na owo ijọba ibilẹ, ṣugbọn ẹgbẹ alatako, PDP, ti n pariwo fun ijọba lati ma gbe igbimọ fidihẹ-ẹ kalẹ.
Jawondo ni idibo kansu naa ko si ninu eto isuna ọdun yii, fun idi eyi, ko too le waye, ijọba gbọdọ gbe e wọ eto isuna ọdun 2021.
O ni oriṣiriiṣii ipenija lo ba ijọba bayii, ara rẹ ni ti ajakalẹ arun Covid-19, owo-oṣu tuntun ati bi ọrọ-aje ko ṣe ṣe daadaa.
Jawondo ni titu ajọ to n ṣeto idibo abẹle, Kwara State Independent Electoral Commission (KWSIEC), ka tijọba ṣe, ṣugbọn tile-ẹjọ fagi le igbesẹ naa tun jẹ ọkan lara awọn idiwọ si eto idibo ijọba ibilẹ ọhun. O ni ẹjọ tijọba pe ta ko idajọ ile-ẹjọ giga ṣi wa nile-ẹjọ ko-tẹmi-lọrun, idajọ gbọdọ waye lori ẹ kijọba too le dawọ le eto idibo naa.