Faith Adebọla
Ileeṣẹ ọlọpaa Eko ti sọ fun gbajugbaja oṣere tiata ilẹ wa kan, Yọmi Fabiyi, atawọn ẹmẹwa rẹ ti wọn jọ ṣewọde fun itusilẹ Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹsa, pe ki wọn ma wulẹ da ara wọn laamu, wọn lawọn o le fi ọkunrin naa silẹ lasiko yii, bẹẹ ni ko saaye fẹnikẹni lati gba beeli ẹ, wọn ni ahamọ awọn lo maa wa titi digba tile-ẹjọ ba silẹkun, ti yoo si balẹ si kootu.
Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu, lo sọrọ yii lọfiisi rẹ l’Ọjọbọ, Wẹsidee, nigba to n sọrọ nipa iwọde to waye naa, o ni ijọba ti ka awọn ẹsun ti wọn maa tori ẹ wọ afurasi ọdaran naa lọ sile-ẹjọ jade, imọran wọn si ni pe ka gbe e lọ sile-ẹjọ, wọn o ni ka ma gba beeli ẹ.
Odumosu ni: “Nigba tawọn oluwọde naa de ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ SCIID lonii (Wẹsidee), Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa to jẹ ọga ẹka yẹn ba wọn sọrọ, o sọ fun wọn pe awọn ọlọpaa ti ṣiṣẹ tiwọn lori ọrọ Baba Ijẹṣa, a si ti fi abọ iwadii wa ṣowo si ẹka eto idajọ, wọn ti gba wa nimọran, imọran wọn si ni pe ka kọwe ẹsun marun-un nipa ọkunrin naa, ka si taari ẹ siwaju adajọ, wọn o ni ka gba beeli rẹ.
“Loootọ ni awọn ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ kootu wa lẹnu iyanṣẹlodi lasiko yii, ti eyi si ti mu ko ṣoro lati wọ ọ rele-ẹjọ tori ilẹkun ile-ẹjọ ṣi wa ni titi, sibẹ a maa tọju Baba Ijẹṣa sahaamọ wa titi tile-ẹjọ fi maa bẹrẹ iṣẹ ni, a si ti gbọ pe wọn ti gba lati din iyanṣẹlodi wọn ku, wọn lawọn maa maa ṣiṣẹ fun ọjọ mẹta, awọn maa yan iṣẹ lodi fun ọjọ meji. “Ọjọ Aje ati Iṣẹgun ni wọn maa yanṣẹ lodi, nigba ti kootu maa ṣilẹkun ni Ọjọruu si ọjọ Ẹti, eyi si fihan pe Baba Ijẹṣa maa dewaju adajọ laipẹ.
“Koda ti iyanṣẹlodi wọn ba tẹsiwaju ju bo ṣe yẹ lọ, eto mi-in maa wa, a si maa gba imọran lori ọrọ afurasi ọdaran yii,” gẹgẹ bi Odumosu ṣe wi.
Tẹ o ba gbagbe, Baba Ijẹṣa ti wa lahaamọ ọlọpaa lati Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹrin, to kọja, latari ẹsun ti wọn fi kan an pe o fipa ba ọmọde, ọmọ ọdun mẹrinla kan laṣepọ, tọrọ naa si da awuyewuye gidi silẹ nigboro.
Bo tilẹ jẹ pe awọn oṣere ẹlẹgbẹ rẹ kan ti faake kọri pe awọn o ni i gba tileeṣẹ ọlọpaa ba gba beeli ọkunrin naa latari bi wọn ṣe n gbọ finrinfinri pe wọn fẹẹ fun Baba Ijẹṣa ni beeli, sibẹ Yọmi Fabiyi atawọn ẹlẹgbẹ rẹ kan ṣewọde alaafia ni Panti, Yaba l’Ọjọruu, wọn ni ko bofin mu bi awọn ọlọpaa ṣe ti ọkunrin naa mọle lai wọ ọ lọ sile-ẹjọ, wọn ni niṣe lawọn ọlọpaa n tẹ ẹtọ rẹ labẹ ofin loju.
Oriṣiiriṣii akọle ni wọn gbe dani, ti wọn si n fi ẹrọ amọhun-bu-gbẹmu kọrin pe ẹtọ Baba Ijẹṣa lawọn waa ja fun. Lara akọle naa ka pe: “Afurasi ọdaran ṣi ni Baba Ijẹṣa, ẹ ma fiya jẹ ẹ bii ọdaran” ati “Ẹ fi Baba Ijẹṣa silẹ tabi kẹ ẹ wọ ọ lọ sile-ẹjọ, atimọle yii to gẹẹ”.