Faith Adebọla
Ofin tuntun kan, eyi ti ileegbimọ aṣofin Eko lawọn maa po pọ, tawọn yoo si ṣagbekalẹ ati amulo rẹ laipẹ, maa da lori didaabo bo ẹtọ ati dukia to jẹ ti awọn ọmọ oniluu, iyẹn awọn ti wọn jẹ ọmọ bibi ilu Eko pọnbele, yatọ sawọn are atawọn ajoji ti wọn wa nipinlẹ naa, tabi awọn ti wọn n rọ wa siluu Eko fun kara-kata ati ọrọ-aje wọn gbogbo.
Olori awọn aṣofin Eko ti wọn ṣẹṣẹ fibo gbe wọle sipo naa, Dokita Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, lo sọrọ yii mimọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹfa, oṣu Kẹfa yii, lasiko to n dupẹ lọwọ awọn ẹlẹgbẹ rẹ fun atilẹyin wọn, ati awọn ololufẹ rẹ ti wọn waa ṣe koriya fun un lọjọ ọhun ninu gbọngan apero wọn to wa l’Alausa, niluu Ikẹja, lakooko ti wọn n fi ijokoo ileegbimọ aṣofin ẹlẹkẹẹwa nipinlẹ Eko, lọlẹ.
Ọbasa ni, “a maa ṣofin, a si maa ṣatunyẹwo awọn ofin to ti wa nilẹ tẹlẹ lori ọrọ okoowo ati ọrọ-aje ṣiṣe l’Ekoo, lori ọrọ dukia, ile ati ilẹ, a maa pa awọn ofin to ba ṣe e parẹ danu lara eyi ta a ti ṣe tẹlẹ lati daabo bo awọn ọmọ oniluu. Ilẹ Yoruba ni ilu Eko, Yoruba lo l’Eko, yatọ si bawọn kan ṣe n sọ ọ kiri pe Eko ki i ṣe tẹnikan, gbogbo wa la l’Ekoo. Tori ẹ, ọkan pataki lara ojuṣe wa ni lati ri i daju pe a tumọ awọn ofin ta a n ṣe l’Ekoo si ede Yoruba pọnbele, a si maa ṣe bẹẹ.”
Ọbasa ṣoju abẹ nikoo pe ofin tuntun to n bọ lọna naa wa fun ẹtọ ati anfaani awọn onilẹ ati oniluu Eko nikan. O sọ pe “afojusun wa ni lati ri i pe a ṣe awọn ofin to fẹsẹ rinlẹ daadaa lati daabo bo awọn eeyan tiwa. Ba a ṣe n tẹsiwaju lori eyi, a maa ri i daju pe a wa inu awọn ofin finni-finni lati ṣatilẹyin to gbopọn fawọn ọmọ bibi ilu Eko, atawọn onilẹ ibẹ.”
Tẹ o ba gbagbe, ọpọ awuyewuye lo gbode lasiko ipolongo ibo gbogbogboo to waye kọja loṣu Keji ati ikẹta ọdun yii, ti ariyanjiyan naa si da lori ọrọ ẹya, ẹsin, ẹgbẹ oṣelu, ẹtọ ọmọ oniluu atawọn ajoji, paapaa niluu Eko.
Nigba ti eto idibo sipo aarẹ waye, ọpọ awọn ẹya Igbo ti wọn n gbe niluu Eko ni wọn ṣatilẹyin fun oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, Ọgbẹni Peter Obi, ti wọn si dẹyẹ si Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, bo tilẹ jẹ pe agba oloṣelu ọmọ Yoruba to filu Eko ṣebugbe, to si ti lo saa meji ọlọdun mẹjọ nipo gomina ipinlẹ naa ni. Tinubu ko wọle ibo aarẹ nipinlẹ Eko lasiko naa, Obi ni ibo rẹ pọ ju.
Ọrọ naa ko yatọ lasiko ibo sipo gomina, bo tilẹ jẹ pe Sanwoolu lo pada wọle, ṣugbọn ọpọ awọn kan ti wọn lẹnu lọrọ lagbo oṣelu Eko dunkooko mọ awọn ajoji, paapaa awọn ẹya Igbo pe wọn ko gbọdọ jade dibo, afi ti wọn ba fẹẹ dibo wọn fun ọmọ Yoruba, Babajide Sanwo-Olu, wọn lọmọ Igbo ni Gbadebọ Rhodes-Vivour ti ẹgbẹ oṣelu Labour, ki i si i ṣe ojulowo ọmọ Eko gidi.