Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Latari iyanṣẹlodi to n lọ lọwọ nipinlẹ Ogun, ijọba ipinlẹ naa labẹ Gomina Dapọ Abiọdun ti lawọn yoo ṣe ohun ti awọn oṣiṣẹ n fẹ lori ẹkunwo ti wọn n beere fun, bo tilẹ jẹ pe obitibiti gbese lawọn ba nilẹ latọwọ ijọba Amosun to kuro nibẹ.
Akọwe ijọba fun gomina, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, lo sọ eyi di mimọ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ninu atẹjade kan ti Kunle Ṣomọrin, akọwe iroyin gomina fi sita. Ọgbẹni Talabi ṣalaye pe bi ajọ to n ṣoju awọn oṣiṣẹ ṣe paṣẹ iyanṣẹlodi lai ti i jẹ kawọn fẹnu ọrọ jona lẹyin ipade tawọn jọ ṣe ko daa rara, o ni iyalẹnu lo jẹ pe wọn le bẹrẹ iyanṣẹlodi nigba to jẹ ọrọ tawọn jọ n sọ ko ti i pari.
O fi kun un pe ki i ṣe pe ijọba Dapọ Abiọdun ko fẹẹ ṣe ohun tawọn oṣiṣẹ naa n beere, ṣugbọn gbese biliọnu ọgọrun-un kan ati mẹfa o le mẹsan-an naira(106.9b)to ni i ṣe pẹlu owo ajẹmọnu, owo ifẹyinti, owo alajẹṣẹku atawọn mi-in bẹẹ ni ijọba tuntun yii ba nilẹ, eyi to jẹ iṣoro lọrun wọn, to si gbọdọ kọkọ ni iyanju na.
Akọwe ijọba Gomina tẹsiwaju pe afikun owo-oṣu ti wọn n beere yii paapaa, ki i ṣe pe ijọba ko ni i san an, ṣugbọn inu oṣu kọkanla, ọdun yii, ni wọn ni lọkan lati bẹrẹ si i sanwo naa fun wọn, awọn eyi to ku si ree, awọn yoo jọ tun un wo ni. Agbẹnusọ ijọba naa sọ pe ko sẹni to mọ pe Korona yoo de, bo ti de lo ko ba bọjẹẹti tijọba ti ṣeto kalẹ, to ko ba ọpọlọpọ nnkan ti araalu paapaa mọ, ṣugbọn bi ẹgbẹ oṣiṣẹ ko ṣe fi eyi ṣe, ti wọn sare bẹrẹ iyanṣẹlodi ojiji ta ko ẹtọ ọmọniyan tijọba ni.
Ṣa, ijọba ipinlẹ Ogun ti bẹrẹ si i yanju awọn owo bii kọpuretiifu ti wọn n yọ lara owo awọn oṣiṣẹ gẹgẹ bi Talabi ti wi, wọn ni awọn n ṣe eyi ko ma baa tun di pe gbese naa yoo maa pọ si i.