Ibrahim Alagunmu, Ilorin
Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti ṣekilọ pe eyikeyii ọdaran ti awọn ba gba mu to n ji dukia ijọba, tabi ba dukia ijọba jẹ, awọn yoo fi irufẹ ẹni bẹẹ jofin.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Ọkasanmi Ajayi, fi sita, eyi to tẹ ALAROYE lo ti ṣeikilọ naa.
O ni awọn ọdaran kan ti bẹrẹ si i ji ẹrọ amuna wa tu ni nnkan bii aago mẹta orun Ọjọruu, Wẹsidee, ni agbegbe ile Adajọ Mustapha Akanbi, niluu Ilọrin, ti wọn si fẹsẹ fẹ ẹ nigba ti wọn kofiri awọn ọlọpaa, eyi ti ko jẹ ki wọn ri ẹrọ ti wọn tu ọhun gbe lọ.
O tẹsiwaju pe awọn ti gbe ẹrọ amunawa naa le awọn alaṣẹ (IBEDC) to wa ni agbegbe (Challenge), n’Ilọrin lọwọ. Ọgbẹni Olumide to jẹ ọga agba ẹka agbegbe ọhun lo tẹwọ gba a lọwọ awọn.
Ni igunlẹ ọrọ rẹ, o parọwa si gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara pe ti wọn ba kẹẹfin iwa aitọ ni agbegbe wọn, ki wọn maa fi to agbofinro leti.