Jamiu Abayọmi
Ọga ọlọpaa patapata nilẹ wa, Kayọde Ẹgbẹtokun, ti pa a laṣẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, labẹ Komiṣanna ipinlẹ naa, Idowu Owohunwa, lati fi awọn ohun eelo igbalode ileeṣẹ naa ṣe iwadii to jinlẹ lori ohun to fa iku ojiji to pa irawọ ọdọmọde olorin ilẹ wa nni, Ilerioluwa Ọladimeji Alọba, ti ọpọ eeyan tun mọ si Mohbad, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii.
Gẹgẹ bi agbẹnusọ apapọ ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa Olumuyiwa Adejọbi ṣe sọ ninu atẹjade kan to fi lede soju opo twitter rẹ l’Ọjọ Abamẹta Satide, ọjọ Kẹrindinlogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2023 yii, nibi to ti n fi abọ ipade ti Ọga ọlọpaa nilẹ wa ati Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko ṣe sita lori ọrọ iku Mohbad lasiko ti wọn lọ ṣe abẹwọ si ẹka ileeṣẹ naa to wa ni papakọ ofuuru Muritala Muhammed towa lagbegbe Ikẹja ipinlẹ naa.
O sọ bayii pe “Ọga ọlọpaa patapata ti paa laṣẹ fun Kọmiṣanna ipinlẹ Eko lati ṣamulo awọn ohun elo igbalode to wa nikawọọ ajọ naa lati fi tuṣu desalẹ ikoko lori awọn ohun to fara sin nipa iku Mohbad, o si ṣeleri atilẹyin ti ko lẹlẹgbẹ fun iwadii naa.”
Tẹ o ba gbagbe, pe ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko gan-an ti kede l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, pe awọn ti bẹrẹ iwadii to rinlẹ lori iku ọdọmọde olorin naa, koda wọn ni tọrọ ọhun ba gba ki awọn hu oku oloogbe naa fun ayẹwo, awọn yoo ṣe bẹẹ.
Lọjọ Abamẹta, Satide, oṣu Kẹsan-an yii, lawọn alaṣẹ ileeṣẹ orin oloogbe naa pe fun idajọ odo lori ohun to ṣokunfa iku eeyan wọn naa, ti wọn si ṣeleri ifọwosowọpọ fun iwadii ọhun.