Adewale adeoye
Meje lara awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye kan ti wọn n da omi alaafia ilu Ijẹbu-Ode, nipinlẹ Ogun ru, lọwọ ikọ akanṣe ọlọpaa kan ti wọn n pe ni ‘Special Weapon And Tactical Team (SWAT) tipinlẹ naa ti tẹ bayii, inu ahaamọ awọn agbofinro ọhun ni wọn si wa titi di ba a ṣe n sọ yii.
Awọn afurasi ọdaran naa lo maa n lọ kaakiri ilu Ijebu-Ode ati agbegbe rẹ, ti wọn si maa n faye ni awọn araalu lara bo ṣe wu wọn.
Awọn afurasi ọdaran naa ni: Balogun Ibrahim, Towolawi Ọmọtayọ, Oṣodi Oluwaṣeun, Nkechi John, Mustapha Aliyu, Ọpẹyẹmi Rasheed ati Mustapha Sikiru.
ALAROYE gbọ pe Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii lọwọ palaba awọn afurasi ọdaran naa segi lagbegbe Ogbo, niluu Ijebu-Ode.
Ọmọ ẹgbẹ okunkun Aiye ni wọn, bẹẹ lo jẹ pe ọpọ idigunjale ati awọn iwa ọdaran gbogbo to n ṣẹlẹ laarin ilu naa ko ṣẹyin wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Kejila, ọdun yii, sọ pe o ti pẹ tawọn ọlọpaa ti n wa awọn afurasi ọdaran naa ko too di pe ọwọ tẹ wọn laipẹ yii.
Atẹjade kan ti wọn fi sita nipa iṣẹlẹ ọhun ni wọn ti ṣalaye pe ‘Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii lọwọ palaba awọn afurasi ọdaran meje kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun Aye segi, agbegbe Ogbo, niluu Ijebu-Ode, nipinlẹ Ogun, lọwọ ti tẹ wọn. Ikọ akanṣe ọlọpaa (SWAT) lo lọọ fọwọ ofin mu wọn nibi ti wọn ṣara jọ si.
‘’Lasiko ta a mu wọn, oniruuru nnkan ija oloro bii ibọn ṣakabula oloju meji, ada, aake, Ida, igi apoola, ọta ibọn ati bẹẹ bẹẹ lọ la ba lọwọ wọn.
‘’ A n ṣewadii nipa wọn lọwọ, a si maa lo awọn ọrọ ta a gba lẹnu wọn lati fi mu awọn ẹlẹgbẹ wọn yooku, lẹyin naa la maa too foju gbogbo wọn pata bale-ẹjọ fohun ti wọn ṣe.