A maa too kapa awọn ẹgbẹ afẹmiṣofo ti wọn ṣẹṣe jade lorileede yii- Tinubu 

Adewale Adeoye

Ki i ṣe iroyin mọ rara pe ẹgbẹ afẹmiṣofo tuntun kan ti wọn n pe ni Lukarawa ti n dalu ru lawọn ipinlẹ bii Ṣokoto ati Kebbi l’Oke-Ọya lọhun-un, ti wọn si n pa awọn araalu naa nipakupa lojoojumọ. Iroyin tuntun to wa nipa awọn eeṣin-o-kọku yii ni pe Olori orileede yii, Aarẹ Tinubu, ti ṣeleri pe laipẹ, laijina, awọn ọmọ ogun orileede yii maa kapa wọn, ti wọn aa si ran wọn pada sibi ti wọn ti wa.

Nibi eto pataki kan to waye laipẹ yii niluu Abuja ni Olubadamọran Tinubu nipa eto aabo abẹle, ‘National Security Adviser’, Ọgbẹni Nuhu Ribadu, ti gbẹnu Aarẹ sọrọ ọhun.

Tinubu ni iṣakoso ijọba oun ko ni i fọwọ lẹran lati maa woran awọn ọmọ ẹgbẹ afẹmiṣofo naa ki wọn maa ṣe ohun to ba wu wọn laarin ilu.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ‘‘Ọwọ ti n ba awọn ọmọ ẹgbẹ Boko Haram, wọn ti n mọ ọn lara, bẹẹ ni wọn ti n sa kijokijo kaakiri, ile ko gba wọn mọ, bẹẹ ni ọdẹ ko gba wọn mọ. Bayiigan-an lo ṣe maa ri fawọn ọmọ ẹgbẹ afẹmiṣofo tuntun Lukarawa yii naa, a maa fọwọ lile mu ọrọ wọn. Abamọ nla lo maa kẹyin ọrọ wọn atawọn to jẹ alatilẹyin wọn.

Ibaṣepọ ti ko si mọ laarin orileede Naijiria ati orileede Niger, nibi tawọn ologun ti ditẹ gbajọba, lo ṣokunfa bawọn ọmọ ẹgbẹ afẹmiṣofo tuntun ọhun ṣe raaye wọ orileede wa, nitori pe ko si ibaṣepọ to daa mọ laarin orileede mejeeji.

Leave a Reply