Faith Adebọla
Ẹgbẹ oṣelu Labour Party, ti ṣekilọ fun ijọba apapọ ati ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), pe ti wọn ko ba dẹkun gbigbegi dina atunyẹwo awọn nnkan eelo ti INEC lo lasiko eto idibo sipo aarẹ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun yii, wọn ni niṣe lawọn maa paṣẹ fawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa lati ya bo gbogbo ẹka ileeṣẹ INEC to wa lagbegbe wọn, ki wọn si bẹrẹ iwọde ati ifẹhonu han to lagbara gidi.
Ọmọwe Yunusa Tanko, ti i ṣe agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo ibo fun oludije funpo aarẹ ẹgbẹ oṣelu naa, Peter Obi, lo fọrọ yii lede lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹta yii, ninu atẹjade kan.
O lo ti foju han gbangba pe niṣe ni ajọ INEC fẹẹ mọ-ọn-ọn so ẹgbẹ awọn lọwọ sẹyin ninu ilakaka awọn lati gba ẹtọ awọn pada, tori ẹ ni wọn ṣe n fẹsẹ palẹ lori aṣẹ ile-ẹjọ to ni ki wọn yọnda fawọn lati ṣatunyẹwo awọn iwe, akọsilẹ ati ẹrọ ti wọn lo lasiko idibo sipo aarẹ to kọja ọhun, ṣugbọn ti wọn ko ko awọn nnkan eelo naa silẹ fawọn bọrọ, ẹyọ-ẹyọ ni wọn n mu un jade.
Atẹjade naa sọ pe: “Lọjọ kẹta, oṣu Kẹta ta a wa yii, la ti mu iwe aṣẹ tile-ẹjọ pa pe ki wọn gba ẹgbẹ wa laaye lati ṣayẹwo si awọn nnkan eelo ti wọn lo lasiko idibo sipo aarẹ to waye loṣu to kọja, lọọ fun INEC, agbẹjọro tiwọn naa si wa ni kootu lasiko ti wọn paṣẹ naa.
“Pẹlu ba a ṣe fun wọn ni aṣẹ tile-ẹjọ pa, ta a tun ti kọ lẹta irannileti mi-in si wọn lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii, ta a si jẹ ki lẹta naa to wọn lọwọ lolu-ileeṣẹ ajọ INEC to wa l’Abuja, lọjọ ta a kọ, niṣe ni INEC n fi aṣẹ naa pa mi-in-din, wọn dagunla si i, wọn o jẹ ka raaye ṣayẹwo naa, o si ya-a-yan lẹnu pe ajọ INEC le diidi gun lagidi si iru aṣẹ ile-ẹjọ banta-banta yii.”
Lẹyin eyi ni wọn sọ pe to ba jẹ pe erongba INEC ni lati gbegi dina fawọn titi tọjọ yoo fi lọ lori atunyẹwo tawọn fẹẹ ṣe ni, awọn o ni i gba, dandan lowo ori, ọran-an-yan laṣọ ibora lawọn yoo sọrọ naa da mọ wọn lọwọ, wọn lawọn maa ya bo gbogbo ẹka ileeṣẹ INEC ni, tawọn ba ti ṣe suuru diẹ si i.
Tẹ o ba gbagbe, ẹgbẹ oṣelu Labour Party ati Peoples Democratic Party (PDP) ni wọn wa nipo kẹta ati ikeji ninu esi idibo sipo aarẹ to kọja lọ ọhun, amọ wọn lawọn ko fara mọ abajade esi idibo naa, wọn lo lọwọ kan eru ninu, n lawọn mejeeji ba kọri sile-ẹjọ, wọn lọọ gba aṣẹ latọdọ igbimọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ ninu idibo sipo aarẹ, iyẹn Tiribunal, lẹyẹ-o-sọka si nigbimọ naa ti paṣẹ pe ki INEC gba gbogbo wọn laaye lati ṣatunyẹwo awọn nnkan eelo ti wọn fi ṣeto idibo naa, ki wọn le wo o boya loootọ ni mago-mago waye abi ki i ṣe bẹẹ. Ọjọ kẹta, ọsu Kẹta yii, ni wọn ti paṣẹ naa.
CAPTION