Jọke Amọri
Ọkan ninu awọn adari ipolongo ibo fun oludije funpo aarẹ egbẹ APC, Festus Keyamo, ti sọ pe awọn ni ẹri to daju lọwọ lati fi han pe ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC ṣeru lasiko ibo to waye ni Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Keji yii.
Lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrindinlọgbọn, lo sọrọ naa. O ni ṣugbọn awọn dakẹ, awọn ko sọrọ, bẹẹ lawọn ko fa wahala, nitori awọn n duro de ki awọn to yẹ lati kede esi idibo ṣe bẹẹ ni, ti awọn ba si ni ohunkohun to lodi si ohun ti wọn gbe jade, awọn aa gbe igbesẹ to yẹ lori rẹ labẹ ofin.
O waa rọ awọn ẹgbẹ alatako pe ki wọn sinmi agbaja, ki wọn yee maa pariwo nibi ti ko si, ki wọn si yee sọrọ to le da wahala silẹ.
Keyamo ni, ‘‘Wọn ti pe akiyesi wa si awọn ọrọ to le da wahala silẹ ti awọn agbẹnusọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati Labour n sọ kiri lori eto idibo to waye lọjọ Abamẹta ti ẹnikẹni ko ti i kede rẹ. Ọpolọpọ wọn ni wọn ti n halẹ, ti wọn si n sọ pe awọn yoo fa wahala, iyẹn ti wọn ko ba kede esi idibo ti atọwọda tiwọn. Awọn ni wọn fẹẹ jẹ olufisun, olugbẹjọ, ti wọn si tun fẹẹ jẹ adajọ lori ẹjọ ti wọn pe funra wọn.
‘‘Siwaju si i, lati jẹ ki awọn eeyan da wahala silẹ, wọn pa irọ jọ pe awọn wahala kan waye nibi ti wọn mọ pe ibẹ la ti lagbara, ti awọn oludibo wa pọ ju si ju lọ, bẹẹ lo si jẹ pe oriṣiiriṣii fidio la ni nipa bi wọn ṣe n halẹ mọ awọn eeyan ti ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ Labour, ti wọn n dunkooko mọ wọn, ti wọn si n paṣẹ fun awọn ọmọde atawọn obinrin lati tẹka fun ọmọ ẹgbẹ Labour. Bakan naa la si ni obitibiti iwe idibo ti awọn alatilẹyin APC ati PDP ti tẹka si.
‘‘Ni afikun si eleyii, ọkan ninu awọn agbẹnusọ ẹgbẹ PDP bu ẹnu atẹ lu iroyin ti iweeroyin kan gbe nipa ẹni to n lewaju, to si n bu ẹnu atẹ lu iweeroyin naa. Bakan naa lo n sọ awọn ọrọ ti ko ni ẹri lati fi gbe e lẹsẹ lori esi idibo ti wọn ko ti i gbe jade ọhun. Ni tiwa, a ti pinnu lati fi ara balẹ, ka si duro de esi ibo ti awọn to yẹ lati kede rẹ yoo ba kede, ka si gba ọna ofin lati fi aidunnu wa han lori esi idibo naa, bi eyikeyii ba wa. Ṣugbọn a ko waa ni tori eleyii kawọ gbera ka maa wo titi ti awọn ọrọ ti ki i ṣoootọ yii yoo fi gbilẹ bii ootọ leti awọn eeyan wa ati ajọ agbaye. Ẹ jẹ ka ranti pe gbogbo ẹgbẹ lo kọwọ bọwe lẹẹmeji ọtọọtọ lati gba alaafia laaye loju gbogbo agbaye. Asiko niyi lati mu adehun naa ṣẹ, ka si fi ifẹ han si orileede wa ju ifẹ ara wa nikan lọ.
‘‘Gbogbo wa la ti polongo ibo kikankikan, awọn ọmọ Naijiria si ti teti si wa, bẹẹ ni wọn ti ṣe ipinnu wọn. Asiko niyi lati gbọ ohun ti awọn ọmọ Naijiria sọ pẹlu esi idibo, ki i ṣe ohun tiwa lo yẹ ki wọn tun maa gbọ mọ. Ajọ kan ṣoṣo ta a si fiṣẹ ran lati ṣọ ohun ọmọ Naijiria jade ni ajọ eleto idibo, ko so si ẹgbẹ to maa halẹ mọ wọn lati ṣe ifẹ inu ti ẹgbẹ wọn. Bẹẹ ni awọn ti inu n bi yii ko le pa ẹnu ẹgbẹ APC mọ.’’
Bẹẹ ni Keyamo pari ọrọ rẹ.