A o ni i faaye gba ẹnikẹni to ba n gbero lati ya kuro lara Naijiria-lleeṣẹ Ologun

Faith Adebọla

 

 

 

Ileeṣẹ ologun ilẹ wa ti kilọ fawọn to fẹẹ gbe igbesẹ ki ẹya kan tabi agbegbe kan da duro, ki wọn ya kuro lara Naijiria, pe ki wọn jawọ ninu iru erongba ati igbesẹ bẹẹ tabi ki wọn mura tan lati koju ibinu awọn ọmoogun ilẹ wa.

Ọga agba fawọn jagunjagun ori ilẹ, Ọgbagun agba Ibrahim Attahiru, lo sọrọ yii lọjọ Aje, Mọnde, nibi akanṣe idanilẹkọọ kan ti wọn ṣe fawọn ologun ilẹ wa niluu Uyo, ipinlẹ Akwa Ibom.

Attahiru ni loootọ lawọn n koju ipenija gidi lori eto aabo lasiko yii, ti ijọba ati awọn ọmọ ogun si n ṣapa gidi lati kaju ẹ, ṣugbọn iyẹn o waa tumọ si pe kawọn eeyan kan bẹrẹ si i lu ilu ipinya ati iyapa, o lawọn o ni i gba ki orileede yii tuka.

“Labẹ idari mi, ileeṣẹ ologun Naijiria maa sapa lati tete gbe igbesẹ, a si maa ṣiṣẹ pelu awọn oṣiṣẹ eleto aabo atawọn agbofinro gbogbo lati le dana ya awọn ti wọn n dun mọhuru-mọhuru mọ orile-ede yii.

“Labẹ idari mi, awọn ọmoogun ti pinnu, a si ti gbaradi ju tatẹyinwa lọ lati gbo ewuro soju ẹnikẹni tabi ẹgbẹkẹgbẹ to ba fẹẹ ṣediwọ fun alaafia, aabo ati ifararọ orileede wa atata yii.”

Lẹyin to sọrọ yii tan lo gba awọn jagunjagun ti wọn kopa ninu idanilẹkọọ naa lati tubọ fara jin fun aabo ati iṣọkan orilẹ-ede yii.

Tẹ o ba gbagbe, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja yii, ni Oloye Sunday Adeyẹmọ, ti wọn n pe ni Sunday Igboho kede niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, pe ẹya Yoruba ti ṣetan lati da duro, ki wọn si ya kuro lara orileede Naijiria, ki wọn di Orileede Olominira Oodua.

Ṣaaju asiko yii ni ajijagbara mi-in lapa ilẹ Ibo, Ọgbẹni Asari Dokubo, ti sọ pe awọn o ni i pẹ da Ijọba Ibilẹ Biafra (Biafra Customary Government) silẹ, ti awọn si maa ya kuro lara Naijiria.

Eyi lọpọ eeyan to gbọ nipa ikilọ ti Ọgagun agba Attahiru ṣe yii fi n sọ pe afaimọ ni ko ma jẹ Sunday Igboho ati Asari Dokubọ lọrọ naa n ba wi.

Leave a Reply