Bi awọn eeyan orilẹ ede yii ṣe n reti ki Aarẹ Muhammed Buhari kede ọga ọlọpaa tuntun bi saa ẹni tó wà níbẹ bayii ṣe pari lójó Ajé, Mọnde, ọsẹ yii, ileeṣẹ Ààrẹ ti sọ pe ko ti ì sí igbesẹ kánkan lori iyansipo ọhun bayii.
Agbẹnusọ fun Ààrẹ Muhammed Buhari, Ọgbẹni Garba Shehu, lo sọrọ yii lórí eto kan nileeṣẹ mohun-maworan Channels TV lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.
Garba Shehu sọ pe, “Ileeṣẹ Aarẹ ko ti i sọ igba kan pato ti yóò kéde iyansipo ọga tuntun fún àwọn ọlọpaa. Ọjọ Ajé, Mọnde, ni ọga patapata lẹnu iṣẹ ọlọpaa, Mohammed Adamu, yẹ ko fẹyinti ninu iṣẹ naa’’
Garba Shehu sọ pé òun kò tí ì mọ̀ ìgbà tí ẹlomi-in yóò bọ sórí ipo ọhun. Bakan naa lo sọ pe ipò ọga ọlọ́pàá kọja ohun ti awọn eeyan gbọdọ máa fojú ẹya kan wo, tabi sọ pe apa ibi kan lo yẹ ko ti wa.
Siwaju si i, agbẹnusọ Aaarẹ ni ọjọ Iṣẹgun ni Aarẹ Muhammed Buhari yoo ṣẹṣẹ pada sẹnu iṣẹ, ati pe yóò fẹẹ to Ọjọruu, Wẹsidee, ko too bẹrẹ iṣẹ.
Bẹẹ lo fi kun un pe oun ko ti ì lè sọ pé ìgbà kan pato ni yóò ṣiṣẹ lori ẹni tí yóò gba ipò ọga agba fún àjọ agbofinro ni Naijiria lẹyin Muhammad Adamu.
O ti waa fi da awọn eeyan lójú pé igbesẹ to yẹ yóò wáyé, bẹẹ ni Buhari yoo yan ẹni tí gbogbo ọmọ Naijiria yóò lè nigbagbọ nla ninu ẹ sẹnu iṣẹ naa.